Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Jiji tawọn ara agbegbe Kọbapẹ, l’Abẹokuta, ji lọjọ Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa yii, oku ọkunrin kan to ti gan sori ọkan lara opo ina to wa laduugbo wọn ni wọn ji ri.
Ko sẹni to mọ ọkunrin naa ri, wọn ko mọ ibi to ti wa, ohun ti wọn kan ri naa ni pe kinni kan ha saarin meji opo ina onirin ọhun, nigba ti wọn si wo o daadaa ni wọn ri i pe gende lẹni to wa nibẹ, o ti ku patapata.
Ohun ti ọpọ eeyan to pejọ sibẹ n sọ ni pe ọkunrin naa mọ-ọn-mọ para ẹ ni, wọn ni o diidi bọ saarin opo ina naa kina le pa a ni.
Ṣugbọn awọn mi-in sọ pe ki i ṣe iku lo wa debẹ, wọn ni waya ina lo fẹẹ ji ka ko too ba ẹbọra to wa nidii ina mọnamọna pade, tiyẹn si yan an gbẹ lẹsẹkẹsẹ.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ti wọn fiṣẹlẹ naa to leti sọ pe oun ko ro pe ọkunrin naa fẹẹ para ẹ ni, o ni ṣebi waya ina to ti ge silẹ lo wa nibẹ yẹn, to ba jẹ pe o kan fẹẹ para ẹ ni, Oyeyẹmi sọ pe yoo kan gun ori opo ni, yoo si di waya ina kan mu, ki i ṣe pe yoo tun ge waya silẹ gẹgẹ bo ṣe wa nisalẹ opo to ku si naa.
O ni o ṣee ṣe ko jẹ ọkan lara awọn ole ti wọn maa n gun opo ina jale lọkunrin yii, ko jẹ pe o ba onile nile niku fi mu un lọ.
Alukoro sọ pe awọn ti gbe oku naa kuro, iwadii si n lọ lori rẹ lọwọ.