Faith Adebọla
Awọn ọrẹ meji kan, Esube ati Solomon Oṣunmuyiwa, ti wọn lawọn n ṣiṣẹ apaayan lagbegbe Ilaro, nijọba ibilẹ Ariwa Yewa, ipinlẹ Ogun, maa to bẹrẹ si i kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ bayii, awọn ọlọpaa ti mu wọn satimọle nibi ti iwadii to lọọrin ti n lọ lọwọ lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.
ALAROYE gbọ pe ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ yii ni ọwọ tẹ ọkan ninu wọn to ni Esube lorukọ oun, wọn lọkunrin naa n gun ọkada lọ lati ọna Papalanto, nijọba ibilẹ Ewekoro lọọ sọna ilu Ilaro ni, o si gbe obinrin kan lẹyin gẹgẹ bii ero, Ọmọwunmi Fiyakọla ni wọn porukọ ero ọhun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, sọ f’ALAROYE ninu atẹjade rẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹsan-an oṣu Kẹjọ yii pe ikọ ọlọpaa ti wọn n patiroolu agbegbe Okeeganmu n’Ilaro, eyi ti Inspekitọ Sunday Adeyẹmọ lewaju fun, ni wọn pade afurasi yii lọna, wọn si wawọ si i pe ko duro, amọ niṣe lo tẹna maṣinni Bajaj rẹ ọhun, ko si si nọmba kankan niwaju ati lẹyin ọkada naa, eyi lo mu kawọn ọlọpaa naa gba fi ya a gidigidi, wọn si le e mu.
Nigba ti wọn da Esube duro, niṣe lo tutọ soke to foju gba a, ija nla lo sọ kalẹ, to si bẹrẹ si i ṣe itaporogan gidi. Tipatipa lawọn ọlọpaa fi raaye tu baagi olokun kan to gbe kọpa, inu baagi ọhun ni wọn ti ba ibọn ilewọ agbelẹrọ kan ati ọta ibọn diẹ nibẹ.
Amọ pẹlu ẹ naa, Esure ko yee fija lọ awọn ọlọpaa yii, bo tilẹ jẹ pe wọn ti wọ ọ ju sinu ọkọ wọn lati gbe e lọ teṣan, wọn niṣe lo deyin mọ ọlọpaa to naka si i lati ki i nilọ, o si fẹrẹ ge ika ọlọpaa ọhun jabọ. Ẹyin eyi lo tun n lọ siarin ọkọ ọlọpaa mọ wọn lọwọ, nibi ti wọn si ti n fa lọgbọlọgbọn ọhun ni taya ọkọ ti bẹ, ni jagunlabi ba fo yọ poki, o ki ere mọlẹ, o fẹẹ sa lọ, amọ wọn ibọn da ẹsẹ ẹtu obeje ẹlẹsẹ ọwọ rẹ duro, eyi lo mu kara rẹ rọ, to fi dero ahamọ ọlọpaa bayii.
Wọn lọkunrin yii ti jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun kan loun ati ọrẹ oun, Solomon, tawọn mejeeji ti wa lakolo ọlọpaa, i ṣe, ati pe iṣẹ apaayan niṣe wọn pẹlu. Wọn tun beere lọwọ ẹ ibi to ti ri ọkada ti ko ni nọmba, o si jẹwọ pe oun ji i ni.
Alukoro ti ni awọn maa foju awọn afurasi yii bale-ẹjọ laipẹ, ẹsun ole jija, ṣiṣe ẹgbẹ okunkun, hihuwa apaayan ati nini ohun ija oloro nikaawọ lai gbaṣẹ ni wọn lawọn maa fi kan wọn niwaju adajọ.