Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo, Ọnarebu Ọladiji Ọlamide, ni wọn ti yan gẹgẹẹ bii olori tuntun fun ileegbimọ ọhun.
Iyansipo yii ni wọn lo waye lasiko ti awọn aṣofin ọhun n ṣe ifilọlẹ ẹlẹẹkẹwaa ile igbimọ naa lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.
Ọmọ bibi ilu Ondo, ni Ọlamide, igba keji si ree ti wọn yoo dibo yan an sipo aṣofin labẹ asia ẹgbẹ All Progressives Congress (APC).
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ni wọn sare tu ile ẹlẹẹkẹsan-an ka lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye kan to jade lọjọ naa lori ikọwe fipo silẹ olori wọn tẹlẹ, Ọnarebu David Bamidele Ọlẹyẹlogun.
Bi iroyin kikọwe fipo silẹ ọhun ṣe n ja ran-in ran-in nilẹ lọwọ ni Ọlẹyẹlogun sare fi atẹjade tirẹ sita, leyii ti oun funra rẹ buwọ lu, nibi to ti sẹ kanlẹ pe oun ko figba kankan kọ lẹta lati fipo olori silẹ, ati pe oun ṣi ni olori ile ọhun.
Ọlẹyẹlogun ni ayederu patapata ni lẹta ti wọn n ka lori ẹrọ ayelujara, bẹẹ lo fi asiko naa ke si ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo lati ṣe iwadii ọrọ naa, ki wọn si mọ ibi ti iwe abami ọhun ti jade sita.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ti kede rẹ pe ile-igbimọ aṣofin ẹlẹẹkẹsan-an ti di tituka, sibẹ, awọn eeyan kan ko yee bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe fẹẹ sare yọ Ọlẹyẹlogun nipo nigba to ku diẹ ki saa rẹ pari.
Ori awọn eeyan kan to sun mọ Gomina Rotimi Akeredolu ni wọn n di ẹbi iṣẹlẹ naa ru, wọn ni ohun ti wọn fẹẹ ṣe ni lati yọ Ọlẹyẹlogun nipo, ki wọn si fi aṣofin mi-in lati Ẹkun Ariwa ipinlẹ Ondo rọpo rẹ.