Bi igbaradi ti ṣe n lọ lori ayẹyẹ ọjọọbi aadọrin (70) ọdun ti Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla fẹẹ ṣe l’Ọjoruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi ati Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, ti ṣapejuwe gomina ipinlẹ Eko ati Ọṣun tẹlẹ yii, gẹgẹ bii ojulowo ọmọ Yoruba to ti sa ipa rere fun ilọsiwaju awọn eeyan ẹ ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ.
Ninu ọrọ ikini ti Alaafin Ọyọ kọ ranṣẹ si ajagun-fẹyinti ati oloṣelu nla ni Naijiria naa ni Ọba Adeyẹmi ti sọ pe ipa rere to ko nipa bo ṣe fi ẹsẹ aṣa mulẹ ati ipo nla to to ipo awọn ọba alaye si pẹlu iṣẹ aṣeyori to ṣe gẹgẹ bii alakooso awujọ lawọn ọmọ Yoruba ko ni i gbagbe laelae, paapaa nilẹ Yoruba.
Ọba Adeyẹmi sọ pe, “Eyi ni ojulowo ọrọ ikini fun Ọmọọba pataki, Ọlagunsoye Aṣọla Oyinlọla, bo ṣe pe ẹni aadọrin ọdun. Ohun to foju han ni pe laarin aadọrin (70) ọdun to ti lo laye yii, ọpọ ohun rere loju rẹ ti ri, atawọn iṣelẹ mi-in ti ara le kọ gẹgẹ bii ẹda eeyan, ṣugbọn ju gbogbo ẹ lọ, gbọn-in-gbọn-in lo duro bii ọkunrin, ti o si ṣe aṣeyọri lori awọn ohun to le da bii okuta idena. Ni tododo, akikanju ati aṣaaju rere ni ẹ lọjọ ti ilẹ ba n pooyi.”
Ọba Adeyẹmi ninu ọrọ ẹ tun sọ pe ipa rere ni Oyinlọla ti ko nipa ilọsiwaju awọn ọba alaye, ati pe titi aye ni Ọlọrun Ọba a maa ṣaponle foun naa, bẹe lawọn ọmọ Yoruba ko ni i gbagbe ẹ nigba kan.
Kabiyesi tun sure fun un pe ki Ọlọrun Ọba tubọ fun un lẹmii gigun ati alaafia, ko le fi wulo fun ilu Okuku ti ṣe ilu abinibi ẹ, ipinlẹ Ọsun, ilẹ Yoruba ati Naijiria lapapọ.
Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Babatunde Ogunwusi, naa ti ṣapejuwe gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla, gẹgẹ bii awokọṣe rere fun gbogbo awọn ọdọ ti wọn n lakaka lati jẹ eeyan laye.
Ninu ọrọ ikini tiẹ lo ti sọrọ ọhun, bẹẹ lo fidi ẹ mulẹ pe bo tilẹ jẹ pe ni kekere piniṣin ni Oyinlọla ti padanu awọn obi ẹ, sibẹ, Ọmọọba ilu Okuku yii ko kuna lati sa ipa lati jẹ eeyan nla loni-in.
Ọba Ogunwusi sọ pe bi Oyinlọla ṣe tẹpa mọṣẹ pẹlu ifarada ko ṣai jẹ ohun iwuri ti eeyan le fi ṣe awokọṣe rere.
O ni, “Ipa rere ni Ọmọọba Oyinlọla ti ko ninu idagbasoke ilu, ṣe eyi to ṣe nigba to wa ninu iṣe ṣọja titi to fi fẹyin ti lọdun 1999 la fẹẹ sọ ni, paapaa lasiko to ṣe gomina ologun nipinlẹ Eko, nibi to ti ṣe awọn aṣeyọri ti ko lẹgbẹ, ti awọn eeyan n sọ nipa rẹ titi doni tabi awọn ohun rere loriṣiiriṣii to mu wọ ipinlẹ Ọṣun wa, nigba to ṣe gomina.
“Yunifasiti ipinlẹ Ọṣun to wa kaakiri awọn ilu nipinlẹ Ọṣun la le pe ni akọkọ iru ẹ to maa ni ọpọ ibudo ni Naijiria, lara awọn oriire nla ti Oyinlọla ko ba ipinlẹ wa niyẹn.“
Ọọni Ile-Ifẹ waa tọrọ ẹmi gigun fun Ọlagunsoye Oyinlọla, bẹẹ lo sọ pe oun nigbagbọ pe titi aye ni Oyinlọla yoo maa ni ipa rere ninu idagbasoke ilẹ Yoruba ati Naijiria lapapọ.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni ayẹyẹ ọhun yoo bẹrẹ, Ọjọ meji gbako ni wọn fẹẹ fi ṣe e pẹlu titẹle ofin atawọn ilana lati fi gbogun ti itankanlẹ arun Koronafairọọsi. Ileejọsin Cathedral Church of Christ, ni Marina, l’Ekoo, ni isin idupẹ yoo ti waye lọjọ kẹta, oṣu keji, ọdun yii, iyẹn Ọjọruu ọsẹ yii, laago mọkanla aarọ.
Bẹẹ gẹgẹ ni isin idupẹ mi-in yoo tun waye ni ileejọsin Ọba Oyinlọla Memorial Anglican Church, Okuku, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, ọsu keji yii, ni deede aago mẹwaa aarọ.
Awọn eeyan nla nla ni yoo peju pesẹ sibi ayẹyẹ yii bii aarẹ orilẹ-ede, awọn gomina, awọn oloṣelu atawọn eeyan nla nla laarin ilu.
Ni bayii, gbogbo ayẹyẹ iwẹjẹ-wẹmu to fẹẹ waye tẹlẹ ni Harbour Point, Victoria Island, l’Ekoo, ni ko ni i le waye mọ bayii nitori ofin ti ijọba gbe kalẹ lati fi dẹkun itakanlẹ arun Koronafairọọsi to gbode kan.