Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Adajọ kootu Majisreeti kan niluu Oṣogbo, ti paṣẹ pe ki Ọlamilekan Adeniji, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, lọọ naju lọgba ẹwọn ilu Ileṣa lori ẹsun jibiti lilu.
Ọlalekan ni wọn fẹsun kan pe o lu ileeṣẹ burẹẹdi Fortunate ni jibiti miliọnu meji aabọ Naira.
Agbefọba, Adegoke Taiwo sọ fun kootu pe laarin oṣu Kọkanla, ọdun 2021, si oṣu Kẹwaa, ọdun 2022, ni olujẹjọ huwa naa lagbegbe KM 10, Dagbolu, loju-ọna Ikirun.
Adegoke ṣalaye pe owo burẹdi to jẹ ti Ọgbẹni Makinde Oluṣeyi ni olujẹjọ naa sọ di ti ara rẹ, eleyii to lodi si ipin irinwo o din mẹwaa abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.
Lẹyin ti olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi ni agbẹjọro rẹ, IfẹOluwa Ayọdeji, bẹbẹ fun beeli rẹ lọna irọrun.
Onidaajọ Abiọdun Ajala waa paṣẹ pe ki olujẹjọ maa lọọ naju lọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ogunjọ, oṣu Kejila, ọdun yii, ti igbẹjọ yoo tun waye lori ọrọ rẹ.