Ọlanrewaju Adepọju, ọga awọn akewi jade laye

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii, lọga awọn akewi Yoruba, to tun jẹ onkọwe ati aṣaaju ẹsin Islam yii, ku sinu ile ẹ to wa ni Idi-Orogbo, lagbegbe Ring Road, n’Ibadan lẹyin ailera ranpẹ.

Nigba to n kede ipapoda baba ẹ, ọmọkunrin baba akewi yii, Alhaji Adejare Adepoju, kọ ọ si ikanni ibanidọrẹẹ (fesibuuku) rẹ, o ni, “Baba ti lọọ sinmi. Inna lilahi Wa innaa ilaehi Roojiuuna (ọdọ Ọlọrun la ti wa, ọdọ Rẹ naa la o pada si. Sun-un-re o, Baba mi.”

Ọlanrewaju Adepọju, ẹni ti awọn iyawo, ọpọ ọmọ ati ọmọ-ọmọ, gbẹyin rẹ lo jade laye lẹni ọdun mẹtalelọgọrin (83).

Aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu yii, ni wọn yoo sinku ẹ ni ilana isinku Musulumi.

Gẹgẹ bi awọn ẹbi alaisi ṣe fidi ẹ mulẹ, lẹsẹkẹsẹ lẹyin isinku ni wọn yoo ṣeto akanṣe adura fun oloogbe naa ni mọṣalaṣi nla kan ti wọn n pe ni UMB, laduugbo Agodi Gate, n’Ibadan.

Ọpọlọpọ ewi iṣiti, ikilọ ati igbani niyanju ni ọkunrin naa ti gbe jade nigba aye rẹ, ko si si ẹni ti ko mọ ọkunrin naa pẹlu bo ṣe maa n fi ewi kilọ iwa fun ijọba ati awọn araalu ti wọn ba n huwa ibajẹ. Bẹẹ ni Olanrewaju Adepọju tun jẹ oṣere, ti oun naa si gbe ere oriṣiiriṣii jade.

 

Leave a Reply