Ọlanrewaju di kọmiṣanna ọlọpaa tuntun nipinlẹ Eko

Adewale Adeoye

Tiluu tifọn lawọn agbofinro fi ki ọga ọlọpaa tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gbe wa sipinlẹ Eko, C.P Ishola Ọlanrewaju. Oun lo gbaṣẹ lọwọ Ọgbẹni Adegoke Fayọade, ti i ṣe kọmiṣanna  ipinlẹ naa tẹlẹ. Oun lo maa jẹ kọmiṣanna ọlọpaa ogoji l’Ekoo.

ALAROYE gbọ pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, nileeṣẹ ọlọpaa orileede yii kede iyansipo Ọgbẹni Ishola Ọlanrewaju gẹgẹ bii kọmiṣana tuntun, bẹẹ ni wọn ti gbe C.P Adegoke Fayọade, ga sipo Igbakeji ọga ọlọpaa, ‘Assistant Inspector-General (AIG), ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Zone 2, to wa ni Onikan, nipinlẹ Eko.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi eleyii mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, sọ pe odu ni kọmiṣanna tuntun ọhun lẹnu iṣẹ ọlọpaa, paapaa ju lọ nipinlẹ Eko, nitori pe aimọye ọdun lo ti lo lẹnu iṣẹ nipinlẹ naa ko too di kọmiṣanna ọlọpaa bayii.

Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iyansipo naa ni wọn ti sọ pe, ‘‘Ọdun 1992 ni Ọlanrewaju darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria. Ko too bẹrẹ iṣẹ ọlọpaa lo ti kawe gboye (B.S.C) ninu imọ ẹkọ Geography, o si tun gboye giga mi-in (MSc) ninu awọn ẹkọ iwe nileewe giga Fasiti Ibadan. Gbara to dara pọ mọ iṣẹ ọlọpaa lo ti n kọ oniruuru ẹkọ nipa iṣẹ agbofinro nilẹ yii ati l’Oke-Okun, eyi si wa lara awọn ohun to sọ ọ di ogbontarigi ọlọpaa bayii.

‘’Yatọ si Fasiti Ibadan to ti kẹkọọ gboye yii, o tun kẹkọọ lawọn ileewe ọlọpaa nipinlẹ Jos, ati l’Abuja. Bakan naa lo ti ṣiṣẹ lawọn ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to lagbara gidi.

Ninu oṣu Kin-in-ni, ọdun 1996 si oṣu Keje, ọdun 2002 lo fi ṣisẹ pẹlu ẹka ileeṣẹ ọlọpaa kan ti wọn n pe ni ‘20 PMF, n’Ikẹja, nipinlẹ Eko. Laarin oṣu Kẹjọ, ọdun 2002 si oṣu Keje, ọdun 2005, o ṣiṣẹ pẹlu ẹka ileeṣẹ ọlọpaa SDQ Commander 23 PMF, ẹka tipinlẹ Eko.

O kẹkọọ gboye nileewe ọlọpaa lọdun 2011, niluu Enugu, lọdun 2013 lo fi wa nileewe ọlọpaa ipinlẹ Kano. Lọdun 2019 si 2021, lo fi kẹkọọ nileewe ọlọpaa ipinlẹ Jos.

Bakan naa lo ti figba kan dipo D.P.O teṣan Sabongida Ọra, nipinlẹ Edo mu, DPO teṣan Igbẹba, nipinlẹ Ogun, DPO teṣan Ibara, nipinlẹ Ogun kan naa.

Ni ti ipinlẹ Eko, o ti figba kan dipo DPO teṣan Gowon Estate mu, DPO teṣan Ibeju Lekki, DPO teṣan Ajah ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Alukoro ti waa rọ awọn araalu Eko pe ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu kọmiṣanna tuntun ọhun, ko le ri iṣẹ naa ṣe.

Leave a Reply