Ọlanrewaju tan ọmọ ọdun mẹsan-an lọ sile rẹ n’Ilẹ-Oluji, lo ba fipa ba a lo pọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti ẹkun kẹtadinlogun, niluu Akurẹ, ti fi pampẹ ofin gbe ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Afọlami Ọlanrewaju, lori ẹsun pe o tan ọmọ ọdun mẹsan-an kan lọ si ile rẹ n’Ilẹ-Oluji, nijọba ibilẹ Ilẹ-Oliji/Oke-Igbo, nibi to ti fipa ba a sun.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Adeoye Akeem to jẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun kẹtadinlogun, pe ọgbọn ni afurasi ọdaran ọhun fi tan ọmọdebinrin ta a forukọ bo laṣiiri naa kuro ni ṣọọbu iya rẹ lọjọ iṣẹlẹ ọhun pe oun fẹẹ fi ọkọ gbe e lọ si ile wọn.
O ni dipo ti iba fi gbe ọmọ naa atawọn aburo rẹ lọ sọdọ awọn obi wọn gẹgẹ bii ileri to ṣe fun wọn, ile ara rẹ lo mori le, nibi to ti fipa ba ọmọ ọlọmọ lo pọ lai fi tawọn aburo rẹ to wa nitosi ṣe.
Akeem ni ni kete to hu iwa ibi naa tan lo ti sare ko gbogbo ẹru rẹ, to si lọọ fara pamọ sibi kan ki ọwọ awọn agbofinro ma baa tẹ ẹ.

O ni ọwọ pada ba ọmọkunrin naa niluu Akurẹ to sa lọ, ti awọn si ti foju rẹ bale-ẹjọ lati jẹjọ ẹsun ifipabanilopọ.

O fi kun un pe awọn ti gbe ọmọbinrin naa lọ sileewosan fun ayẹwo ati itọju, ko too di pe awọn foju afurasi ọhun ba ile-ẹjọ giga to wa l’Akurẹ.

Leave a Reply