Ọlasunkanmi at’ọrẹ ẹ dero ẹwọn, ile-epo ni wọn lu ni jibiti miliọnu rẹpẹtẹ l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Lori ẹsun lilu jibiti ati fifi ọgbọn eke gba owo lọwọ eeyan, ile-ẹjọ Majisreeti kan to wa ni Ado-Ekiti, ti paṣẹ pe ki awọn meji kan, Ọlanipẹkun Ọlasunkanmi, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn (34), ati Adeboye Ọlabayọ, ẹni ogoji ọdun (40) lọọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn bayii.

Awọn eeyan naa ni wọn fẹsun pe wọn lu ile epo kan ni jibiti owo to to ogoji miliọnu Naira ni Ado-Ekiti.

Gẹgẹ bii iwe ẹsun ti wọn fi kan wọn, ALAROYE gbọ pe niṣe ni wọn gbimọ-pọ lati  ṣẹ ẹsẹ yii lọjọ kejila, oṣu Karun-un, ọdun yii, niluu Ado-Ekiti. Ẹsun yii ni ile-ẹjọ juwe gẹgẹ bii ohun to lodi sofin orilẹ-ede Naijiria ti wọn kọ lọdun 2006.

Lẹyin ti wọn ka iwe ẹsun naa si wọn leti ni agbẹjọro wọn, Ọgbẹni Dọtun Ọmọtẹyẹ ati Arabinrin Funmilayọ Akinwumi, bẹ kootu pe ki wọn yọnda awọn onibaara awọn wọnyi fun awọn, pẹlu ileri pe wọn ko ni i sa lọ.

Ṣugbọn arọwa ti Agbefọba, Ọgbẹni Ojo Osubu, rọ kootu ni tiẹ ni pe ki adajọ paṣẹ pe ki wọn maa ko awọn ọdaran naa lọ si ọgba ewọn titi ti awọn yoo fi gba imọran lọwọ ẹka to maa n gba ile-ẹjọ nimọran.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ A.O Owolẹsọ paṣẹ pe ki awọn ọdaran naa maa lọọ gbatẹgun lọgba ẹwọn fun ọgbọn ọjọ gbako, titi imọran yoo fi jade latọdọ ijọba

Lẹyìn eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2024.

Leave a Reply