Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn agbofinro ijọba ipinlẹ Ọyọ, iyẹn Operatipon Burst ati ikọ Amọtẹkun, titi dori awọn ọlọpaa ti wọn jẹ oṣiṣẹ ijọba apapọ ni wọn ti n fọ inu igbo kaakiri ipinlẹ naa bayii lati tu awakusa ti wọn ji gbe lọ kuro ninu igbekun awọn ajinigbe.
Lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lawọn ajinigbe ọhun ya wọ ibi ti awọn ti n wa okuta laduugbo Mọniya, n’Ibadan, ti wọn si ji ọkan inu awọn oṣiṣẹ ọhun gbe.
Oludari ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ, Ọgagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju, ẹni to kọkọ fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan, sọ pe bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye ni wọn ti fi to awọn leti, lẹsẹkẹsẹ lawọn si ti ya lu gbogbo igbo to sun mọ Mọniya lati gba obinrin ti wọn ji gbe ọhun lọwọ awọn ajinigbe.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, lo pada tan imọlẹ si iṣẹlẹ ọhun laaarọ yii, to jẹ ki gbogbo aye mọ pe obinrin lẹni ti wọn ji gbe ọhun, ati pe Agboọla Damilọla lo n jẹ.
Damilọla yii ni SP Fadeyi pe ni ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ awakusa ti wọn n pe ni Delydad Quarry, loju ọna atijọ ti wọn n gba ti Ibadan lọ siluu Ọyọ.
Awọn ọlọpaaa naa ti dara pọ mọ ikọ agbanila to n fọ inu igbo kiri bayii lati gba obinrin ti wọn ji gbe ọhun silẹ, o waa rọ ẹnikẹni to ba ni iroyin to le ran awọn agbofinro lọwọ lori akitiyan wọn naa lati fi to awọn ọlọpaa leti loju ọjọ.