Ọlọkada wa iwakuwa, ni mọto ba pa a l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

 

Nitori bo ṣe fẹẹ ya ọkọ ayọkẹlẹ Mitsubishi kan silẹ niwaju ọfiisi awọn DSS, l’Oke Mosan, l’Abẹokuta, lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, oṣẹ yii, ọkunrin ọlọkada kan riku ojiji he nigba ti mọto to fẹẹ ya silẹ naa gba a, to si pa a loju ẹsẹ.

Awọn tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn ṣalaye pe ni nnkan bii aago kan ọsan kọja iṣẹju mẹẹẹdọgbọn lo ṣẹlẹ. Wọn ni niṣe ni ọkada ti ko ni nọmba naa n sare buruku, mọto to fẹẹ ya silẹ ni wọn pe nọmba tiẹ ni JJJ 304 FD.

Bi ọlọkada yii ṣe fẹẹ ya mọto naa silẹ lọna aitọ lo di ọran si i lọrun, to fi di pe niṣe lo fẹgbẹ lelẹ, to ṣubu lọ tuurutu. Mọto to fẹẹ ya silẹ lo si pada ṣe e ni ṣuta.

Bi eyi ṣe ṣẹlẹ ni ọlọkada naa dagbere faye, bẹẹ lọkunrin kan naa to gbe sẹyin ṣeṣe pupọ, ko le fẹsẹ rẹ rin, awọn oṣiṣẹ TRACE to wa nitosi ni wọn gbe e lọ sọsibitu jẹnẹra to wa n’Ijaye, wọn si gbe oku ọlọkada to ku naa fawọn ẹbi ẹ lati lọọ sin.

Leave a Reply