Ọlọkada yii loun ko fẹẹ ri ọdun 2025, eyi lohun to ṣe funra ẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nigba ti gbogbo aye n gbadura lati la ọdun 2024 to n pari lọ yii ja, ti olukuluku si n ṣe ipinnu ohun meremere to fẹẹ ṣe lọdun 2025 to n bọ lọna silẹ, ko sohun meji to wu ọkunrin ọlọkada kan, Fatai Hamzat, lọkan ju iku lọ ni tirẹ, o ni ni toun, oun ko tilẹ fẹẹ ni nnkan kan an ṣe pẹlu oṣu Kejila ọdun yii, debi ti oun yoo di ọdun titun ti wọn n pe ni 2025 naa laye.

Kiakia lo si mu ileri buruku ọhun ṣẹ, ko ju ọjọ kan pere lọ ka wọnu oṣu Kejila yii lọ ni jagunlabi mọ-ọn-mọ gbẹmi ara ẹ, to si ṣe bẹẹ dero ọrun alakeji.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, laarin oru mọju ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn (29), oṣu kọkanla, to kọja yii, lọkunrin naa pa kóróbójó okun lo ba yanju ara ẹ, o si gbọna ọrun lọ.

Ni nnkan bii agogo meje aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja la gbọ pe wọn ba oku ẹ to n rọ dirodiro nibi to para ẹ si laduugbo Ọrẹmeji, lagbegbe Ijẹun-Titun, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, to n gbe.

Ọkan ninu awọn aladuugbo rẹ to wa a lọ sile laaarọ ọjọ naa lo jẹ ki wọn mọ pe o ti ku. Igba to kanlẹkun, kanlẹkun yara ẹ, ṣugbọn ti ko rẹni da a lohun.

Niwọn igba to si jẹ pe inu ọgba ile to n gbe naa lọkada rẹ wa, awọn aladuugbo rẹ mọ pe inu ile naa lo wa, paapaa nigba to jẹ pe ẹyin ni wọn ti ilekun yara naa si. Eyi lo mu ki wọn yọju wo inu yara ẹ lati oju ferese, ti wọn si n wo oku ọkunrin naa labẹ faanu loke aja lọọọkan.

Lẹyin naa ni wọn fipa jalẹkun  wọnu yara ẹ, ko too di pe wọn gbe oku ẹ sọ kalẹ lati sin lẹyin ti wọn pari awọn eto gbogbo to yẹ.

Titi ta a fi pari pari akojọ iroyin yii, ko sẹni to ti i mọ pato ohun to ṣokunfa bi gendekunrin naa

ṣe deedee gbẹmi ara rẹ.

Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ lorukọ CP Abiọdun Alamutu ti i ṣe ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Ọmọlọla Odutọla, ṣalaye pe “Awọn ọlọpaa ti gbe oku naa lọ si mọṣuari fun ayẹwo tawọn oloyinbo n pe ni “autopsy”.

“Iwadii ti n lọ lọwọ lati mọ idi tọkunrin naa fi gbẹmi ara ẹ.”

Leave a Reply