Ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori ọmọkunrin tawọn ọlọkada Hausa dana sun nitori ọgọrun-un Naira ni Lekki

Monisọla Saka

Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lati ṣawari awọn Hausa ọlọkada to lu ọmọkunrin kan torukọ re n jẹ David pa, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un yii, lagbegbe Lekki Phase 1, niluu Eko, nitori ọgọrun-un Naira.
Ọdọmọkunrin onimọ ẹrọ nipa orin ni wọn pe ọmọkunrin ti awọn awọn ọlọkada kan ti wọn jẹ Hausa, dawọ jọ lu pa, ti wọn si tun dana sun oku ẹ, nitori ede aiyede to bẹ silẹ laarin wọn lori ṣẹnji ọgọrun-un Naira.
Gẹgẹ bi awọn ti ọrọ ṣoju wọn ṣe wi, ṣẹnji ọgọrun-un Naira lo bi fa-n-fa to di wahala laarin David ati ọlọkada to jẹ ọmọ ilẹ Hausa naa.
Lojiji ni awọn ọlọkada ẹgbẹ ẹ rọ de lati waa gbeja ọmọ iya wọn, niṣe ni gbogbo yọ igi ati kumọ, ti wọn si bẹre si i ko o bo ọmọkunrin yii atawọn ọrẹ rẹ nilukulu, wọn lu wọn titi ti awọn yẹn o fi le minra mọ.
Lati ile igbafẹ kan ti wọn n pe ni Beer-bar, lagbegbe Admiralty Way, ni David pẹlu awọn ọrẹ ẹ ti jọ lọọ ṣiṣẹ, lasiko ti wọn n dari bọ wale ni wọn gun ọkada. Ọkada ti wọn gun naa la gbọ pe o fa wahala nitori ṣenji ọgọrun-un Naira ti ẹnikẹni ko ti i le sọ bo ṣe ṣẹlẹ.
Ninu fido kan ti wọn gbe sori ẹrọ ayelujara ni aṣiri bi wọn ṣe lu ọmọkunrin naa atawọn ọrẹ ẹ ṣe tu. Awọn ọlọkada Hausa naa pọ niye, niṣe ni wọn si n ju oko, ti wọn n la igi mọ David to ti ṣubu lulẹ naa lori ati ni gbogbo ara ti wọn si pada sun oku David nina loju titi nibẹ.
Ọrẹ David ta a forukọ bo laṣiiri sọ pẹlu itara pe ọna ati-jẹ ni ọrẹ oun ba lọ ki awọn Hausa ọlọkada too da ẹmi ẹ legbodo, ti wọn si jẹ ki ọkunrin naa kanju lọ sọrun lai jẹ ko duro ṣe baba fawọn ọmọ ẹ meji to fi silẹ lọ.
Ọgọọrọ awọn ọmọ Naijiria lori ẹrọ ayelujara ni wọn n pe fun idajọ ododo lori awọn ti wọn gbẹmi David, ti wọn si tun dana sun un pẹlu awọn ọrẹ ẹ ti wọn wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun nileewosan lọwọlọwọ bayii.
Ohun ti wọn n sọ ni pe o jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ pe awọn eeyan naa yoo ti Oke Ọya waa maa pa awọn alaiṣẹ ni ilẹ Yoruba nibi, ohun ti ẹnikẹni ko le dan wo ni adugbo tiwọn.
Wọn ke si ijọba lati ṣe idajọ ododo to tọ fawọn ti wọn pa David ati Deborah Samuel nipinlẹ Soko

Leave a Reply