Monisọla Saka
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe awọn ti doola awọn ọdọmọdekunrin mẹrin kan ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹrindinlogun (16) si mejidinlogun (18). Bẹẹ ni wọn ni awọn ti mu afurasi ọdaran to mu wọn nigbekun lagbegbe Surulere, nipinlẹ naa.
Agbẹnusọ ọlọpaa Eko, Benjamin Hundenyin, lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade to fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kọkanla, ọdun yii. O ni awọn ti ṣatọna bi awọn ọmọ naa ṣe pada sọdọ awọn ẹbi wọn.
Awọn ọmọ yii, ni Hundenyin sọ pe wọn ri ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ kọja iṣẹju mẹwaa lọjọ Abamẹta, Satide, nibi kọlọfin kan to da paro ninu papa iṣere nla National Stadium, Surulere, l’Ekoo. O lọgaa agba awọn ẹṣọ papa iṣere ọhun ni Ọlọrun fi ṣe angẹli wọn, oun lo ri wọn lasiko ti wọn n yika inu papa iṣere naa, to si pe agọ ọlọpaa agbegbe yii lati ṣalaye ohun toju ẹ ri fun wọn.
Benjamin ni iwadii tawọn agbofinro ṣe fihan pe lati agbegbe Ọgba ati Agege, nipinlẹ Eko, lafurasi naa ti fọgbọn tan awọn ọmọ yii wa si Surulere.
O fi kun un pe lasiko ti wọn gba awọn ọmọkunrin naa silẹ lawọn ọlọpaa teṣan agbegbe Surulere fi panpẹ ofin gbe ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelaaadọta kan, Austin Kanu, to ji wọn gbe pamọ.
Nigba ti wọn si pe awọn obi wọn, inu wọn dun, wọn si fẹmi imoore han. Wọn ni lati aarọ kutukutu ọjọ Abamẹta, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, to kọja yii, lawọn ọmọ naa ti dawati, tawọn si ti daamu gidi gan-an lati le ri wọn laaye ati alaafia ara.
Iwadii ṣi n tẹsiwaju, ni kete ta a ba si ti pari ẹ ni wọn yoo foju afurasi ọdaran naa bale ẹjọ”.
Hundenyin waa gba awọn ọmọ Naijiria nimọran lati maa kiyesara nitori oju lalakan fi i ṣọ’ri, ki wọn si tete maa fi ohunkohun to ba mu ifura lọwọ layiika wọn to awọn oṣiṣẹ eleto aabo leti.