Florence Babaṣọla
Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, ASP Yẹmisi Ọpalọla ti sọ pe eeyan meje ni wọn ku lasiko wahala idigunjale to waye niluu Ikire ati Apomu lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Ọpalọla ṣalaye pe ọlọpaa meji, awọn afara-jọlọpaa (Constabularies) meji ati awọn araalu mẹta ni wọn ba iṣẹlẹ naa lọ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn ọlọpaa naa ni ASP Ọṣhọ Oluranti ati Inspẹkitọ Lekan Ọlalere, nigba ti Ọladeni Ọlalekan ati Oyedeji Muyideen jẹ ọmọ ikọ afara-jọlọpaa.
Toheed Oyebọla, Tẹmilọrun Adebiyi ati ọkunrin kan ti wọn ko ti i mọ orukọ rẹ fara gbọta lasiko ti awọn adigunjale naa n sa lọ nigba tawọn agbarijọ ikọ agbofinro atawọn ọdẹ doju kọ wọn.
O fi kun ọrọ rẹ pe aago mẹfa irọlẹ kọja iṣẹju mẹwaa ni awọn adigunjale naa, ti wọn to marundinlogoji de agbegbe naa ninu mọto marun-un ti wọn gbe wa.
Ikire Divisional Police Headquarters ati ọkọ akọtami (Armoured Personnel Carrier) to wa lorita Ikoyi ni wọn kọkọ doju ibọn kọ, lẹyin ti wọn ṣe awọn ọlọpaa ibẹ ṣibaṣibo ni wọn pin ara wọn si ileefowopamọ First Bank ilu Ikire ati Access Bank to wa niluu Apomu.
Awọn nnkan ija oloro bii danamaiti la gbọ pe wọn gbe wa, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ni wọn ko ri owo ko lawọn ileefowopamọ naa, sibẹ, wọn fọ gbogbo ilẹkun abawọle ileefowopamọ First Bank, Ikire.
Ọpalọla ni ọpọlọpọ awọn adigunjale naa fara gbọta, ti wọn si sa wọnu igbo lọ, nigba ti awọn to ku ri mọto mẹta pere gbe lọ lara mọto marun-un ti wọn gbe wa.
O ni wọn ti gbe oku awọn eeyan mejeeje ọhun lọ sile igbokuu-pamọ-si ti ileewosan Oluyoro Catholic Hospital, Apomu, nigba ti awọn ọlọpaa ṣi n dọdẹ awọn adigunjale naa.