Ọlawale Ajao, Ibadan
Yoo ṣoro ki obinrin ọlọpaa kan, Abilekọ Ọmọlọla, too le wẹ ara rẹ mọ kuro ninu ẹsun ipaniyan, pẹlu bi wọn ṣe fura si i gẹgẹ bii ẹni to pa ọmọbinrin ọmọọdun mẹrinla kan, Tọmiwa Ajayi.
Ọmọlọla, ọlọpaa to fi adugbo General Gas, n’Ibadan, ṣebugbe, lo gba Tọmiwa sọdọ gẹgẹ bii ọmọọdọ fun itọju ile ati ọmọ rẹ kekere.
Ṣugbọn ko ju oṣu mẹwaa pere lọ ti ọmọọdọ yii de ile ọga ẹ ti obinrin ọlọpaa naa fi gbe oku ẹ ranṣẹ si awọn obi ẹ.
Awọn to ri Tọmiwa lẹyin to ku tan royin pe oku ọmọbinrin naa ko ṣee ri, nitori ara rẹ jẹ kiki oju egbo ati apa loriṣiiriṣii.
Ohun to si ko ba ọga ẹ to n jẹ Ọmọlọla ree, nitori awọn ẹbi ọmọ naa gba pe iya to fi n jẹ ọmọ awọn lo da awọn apa to wa lara oku ọmọ naa sibẹ.
Ọmọ bibi orileede Benin, to fi ipinlẹ Ogun ṣebugbe, ni iya Tọmiwa, Abilekọ Yẹmisi Jimoh. Ọmọ yii lo ti kọkọ bi fun ọkunrin kan ko too wọle ọkọ. Ọdọ aburo iya ẹ to n jẹ Fatai lọmọ naa n gbe.
Iyawo Fatai to n jẹ Kẹhinde Ojo lo mọ bi ọmọbinrin ẹni ọdun mẹrinla naa ṣe de ọdọ Ọmọlọla ọlọpaa, nigba ti obinrin agbofinro naa nilo ọmọọdọ.
Nigba to n royin bi wọn ṣe fi ina ọmọ jo o, Yẹmisi, iyẹn Iya Tọmiwa, ṣalaye pe “Ninu oṣu Keji, ọdun yii, niyawo aburo mi waa ba mi pe ọlọpaa kan nilo ọmọọdọ.
“Mo gba pe ki ọmọ mi lọọ maa ṣe e ṣugbọn mo ni mi o fara mọ ko maa fun un lowo, ohun ti mo fẹ ni ki wọn ṣaa ti maa ba mi tọju ẹ, ki wọn si jẹ ko kawe tabi ko kọṣẹ telọ, ọga ẹ si sọ pe oun fara mọ ọn.
“Mi o ti i foju kan ọmọ mi lati inu oṣu Keji to ti wa pẹlu obinrin yẹn, afi bo se di ọjọ Jimọ to kọja to gbe oku ẹ waa ba mi nile.
Ni nnkan bii ọjọ mẹta kan ṣaaju iku ọmọ mi lọkan mi bẹrẹ si i fa si i. Nigba ti mo pe ọga ẹ pe ki n le gbọ ohun rẹ, nọmba yẹn ko lọ rara”.
Ninu ọrọ tiẹ, Kẹhinde Ojo (Iyawo aburo Yẹmisi) sọ pe oun naa ko mọ Ọmọlọla tẹlẹ, ọrẹ oun kan lo sọ foun pe o nilo ọmọọdọ ti oun fi pe Iya Tọmiwa, ti iyẹn fi gba pe ki ọmọ oun lọọ ṣiṣẹ naa.
“Lati inu oṣu Keji ti Tọmiwa ti wa nibẹ, gbogbo igba ti iya ẹ ba ti fẹẹ ba a sọrọ, ọdọ mi lo maa n wa, ti ma a fi foonu mi pe obinrin yẹn pe a fẹẹ ba Tọmiwa sọrọ.
“Lọsẹ to kọja niya Tọmiwa duro le mi lọrun pe oun fẹẹ ba ọga ọmọ oun sọrọ. Ṣugbọn o da bii ẹni pe obinrin yẹn ko fẹẹ gbe ipe wa ni nitori ta a ba pe e, nọmba yẹn ki i lọ, a si le pe e nigba mi-in ko sọ pe wọn n lo nọmba yẹn lọwọ.
“Nigba to ya l’Ọmọlọla funra rẹ pe mi, o ni oun fẹẹ ba mi sọrọ nipa Tọmiwa, ṣugbọn oun ko fẹ ki ẹnikẹni gbọ si i. Nigba yẹn lo sọ fun mi pe Tọmiwa ti ku, o ni ẹsẹ kan lo n dun un, ati pe ṣe awọn le gbe oku ẹ wa, mo si ni ko si wahala”.
Ṣugbọn nigba ti wọn maa gbe oku ẹ de, awọn agba mẹta kan l’Ọmọlara ran wa lati Oke Anglican, niluu Ilaro lati waa pẹtu si wa ninu.
Wọn ni Ibadan lẹni to ran awọn wa wa, ṣugbọn nigba ti wọn n lọ, mo dọgbọn gbe ọkada tẹle wọn lẹyin, mo si ri i pe ọdọ Omọlara ni wọn pada si nibi to ti n duro de wọn niluu Ilaro yii kan naa.
“Bi mo ṣe pariwo mọ Ọmolara niyẹn, mo ni iwọ lo pa Tọmiwa. Bo ṣe bẹrẹ si i gbọn niyẹn. Iyẹn lo jẹ ki iya mi lọọ fi iṣẹlẹ yẹn to awọn ọlọpaa teṣan Ilaro leti lọjọ Ẹti, Furaidee.
Akitiyan wa lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lọdọ DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ko seso titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.
Ki ni wọn ti ṣe oku Tọmiwa si? Njẹ awọn ọlọpaa ti mu ọlọpaa ẹgbẹ wọn ti wọn fẹsun ipaniyan ọhun kan? Ibeere wọnyi ati gbogbo iwadii ta a ba tun ṣe lori iṣẹlẹ yii ALAROYE yoo maa ṣalaye nigba to ba ya.