Ọlọpaa ka ale mọ ori iyawo ẹ, lo ba yinbọn pa awọn mejeeji

Faith Adebọla

 Orin agba oṣere onisakara ilẹ Ẹgba kan, Yusuf Ọlatunji, to ni ‘a ki i fọkọ han ale, a ki i fale ẹni han ọkọ’ ti ja sootọ pẹlu iṣẹ aburu kan to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa yii. Ọlọpaa ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta kan, Fair Muleya, ni wọn lo ka ale mọ ori iyawo rẹ ninu ile wọn, lo ba yinbọn pa awọn mejeeji.

Agbegbe kan ti wọn n pe ni Dundumwezi Zawa Camp, lorileede Zambia niṣẹlẹ ọhun ti waye.

Iyawo ọlọpaa yii, Precious Moono Hamaindo, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, loun ati ale rẹ, Ọgbẹni Wisdom Pinto, jọ n ṣe wọlewọde.

Gẹgẹ bi kansẹlọ Wọọdu Katanda, Ọgbẹni Maxley Kasusuli, ṣe fidi ẹ mulẹ, o lọlọpaa yii ti n gbọ finrin-finrin tẹlẹ nipa agbere to n waye laarin iyawo rẹ ati oloogbe to n yan lale ọhun, ṣugbọn laṣaalẹ ọjọ kan lo ka wọn mọ.

Ọjọ a ba ribi nibi i wọlẹ ni wọn lọlọpaa yii fọrọ ọhun ṣe, niṣe lo pe awọn mejeeji lọkọọkan, o si yinbọn ọwọ rẹ fun wọn.

Lẹyin eyi ni wọn lo pe ọrẹ ẹ kan ti wọn jọ n ṣiṣẹ ọlọpaa, o sọ ohun to ṣẹlẹ fun un, lo ba pe ọlọkada kan, o ni ko gbe oun lọ si teṣan.

Wọn loun funra ẹ lo lọọ fẹnu ara ẹ jẹwọ aburu to ṣe.

A gbọ pe wọn ti gbe oku awọn mejeeji yii lọ sile igbokuusi Kalomo Urban Clinic Mortuary, fun ayẹwo iṣegun, wọn si ti fi afurasi ọdaran to fibọn gbẹmi wọn sahaamọ fun iwadii.

Leave a Reply