Ọlọpaa kankan ko gbọdọ tẹle awọn oloṣelu tabi olowo kaakiri lọjọ ibo-Ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti jawee akiwọwọ fun awọn oṣiṣẹ rẹ pe eyikeyii ninu wọn to ba tẹle awọn oloṣelu tabi awọn eeyan pataki lọjọ idibo yoo fimu danrin.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Yẹmisi Ọpalọla, fi sita lo ti sọ pe ko saaye fun awọn ọlọpaa ti wọn wa pẹlu gomina, minisita atawọn oṣiṣẹ ijọba lati tẹle awọn ọga wọn lọ sibudo idibo ninu idibo yii.

Ọpalọla ṣalaye pe ọlọpaa to ba tasẹ agẹrẹ si ofin yii yoo jẹyan rẹ niṣu nitori awọn ko ni i fojuure wo iru ẹni bẹẹ.

Bakan naa lo ni ko saaye fun fifọn sairin (Siren), gilaasi alawọ dudu (tinted cars) ati bẹẹ bẹẹ lọ lasiko idibo.

Atẹjade naa tun kilọ fun gbogbo awọn ikọ alaabo ti ofin ko fọwọ si lati kopa ninu idibo lati yẹra fun ipinlẹ Ọṣun patapata.

Nitori idibo yii, ileeṣẹ ọlọpaa fi nọmba meji lede eyi ti awọn araalu le pe si ti wọn ba kẹẹfin ohunkohun, awọn nọmba naa ni; 08039537995, 08075872433 ati 08123823981.

 

Leave a Reply