Faith Adebọla
Bii-kiku-bii-yiye ni awọn ero rẹpẹtẹ ti wọn wa nibudokọ Ketu, lọna marosẹ Ikorodu, nijọba ibilẹ Koṣọfẹ, dawọ jọ lu ọlọpaa kan tọwọ wọn ba lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ yii, wọn si lu agbofinro naa debi to fi daku ti wọn tun n rọ omi le e lori ko ma lọọ gbabẹ sọda, ẹsun ti wọn fi kan oun ati ẹlẹgbẹ rẹ kan tiyẹn ribi sa mawọn eeyan tinu n bi naa lọwọ ni pe, wọn niṣe ni wọn n le awakọ ero kan, wọn fẹẹ gba mọto ẹ, ibi ti wọn si ti n le e rabaraba lati mu un ni wọn ti le ọkunrin naa si ọna akanṣe ọkọ BRT ijọba, niṣe lọkunrin naa ṣe kongẹ ọkọ BRT to n bọ, niyẹn ba gba a bii bọọlu siwaju, o si tun tẹ ẹ mọlẹ.
Ẹnikan to mo awakọ yii, tiṣẹlẹ naa si ṣoju rẹ sọ pe Yusuf lorukọ dẹrẹba ti wọn le ọhun, amọ ori ko o yọ, wọn ni ko ti i ku titi dasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ, bo tilẹ jẹ pe ọkọ BRT naa ti ṣe e leṣe pupọ, niṣe ni gbogbo ara rẹ fa ya pẹrẹpẹrẹ, ti ẹjẹ si n da lara rẹ, gbogbo aṣọ ọrun ẹ lo ti di akisa pẹlu bi ọkọ ọhun ṣe gbo o mọlẹ.
Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe ọna Ikosi ni Yusuf ti n bọ, lile ti wọn le e nileekulee lo mu ko jana mọ ọkọ BRT tiyẹn n bọ lati Ikorodu lẹnu, ti ijamba naa fi ṣẹlẹ.
Wọn ni ariwo ‘haa, ikunlẹ abiyamọ o’ tawọn eeyan tọrọ ọhun ṣoju rẹ pa lo mu kawọn ọlọpaa naa dẹyin lẹyinm ọkunrin ti wọn le sẹnu ọkọ yii, eyi ti wọn iba fi ṣaajo rẹ, n ni wọn ba n sa lọ, amọ ọwọ tẹ ọkan ninu wọn.
Mimu ti wọn mu ọlọpaa yii, niṣe lawọn eeyan ọhun ṣuru boo bii igba ti ijalọ, wọn bẹrẹ si i lu u lalubami, bawọn kan ṣe gba a lẹṣẹẹ, lawọn kan n fi bẹliiti luu, awọn mi-in tiẹ n fi igi lu u pẹlu, wọn fibinu fa aṣọ yunifọọmu ọrun ẹ ya, iya ọhun si pọ debi to fi daku mọ wọn lọwọ, ki wọn too dẹyin lẹyin ẹ.
Bakan naa lawọn alaaanu ara Samaria kan ṣuru bo Yusuf ti BRT gba, wọn gbe e kuro ninu ọgbara ẹjẹ, wọn si ṣeto lati gbe e lọ sọsibitu kan nitosi ki wọn le doola ẹmi ẹ.
Wọn ni lẹyin ti awuyewuye naa rọlẹ diẹ, lawọn alaaanu kan bẹrẹ si i rọ omi le ọlọpaa naa lori, awọn ọlọpaa ẹlẹgbẹ rẹ lati ẹka ileeṣẹ wọn to wa ni Ketu, ti ko fi bẹẹ jinna sibi tiṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ jade wa, wọn si ṣaajo ẹni wọn.
Bakan naa lawọn ọlọpaa rẹpẹtẹ ti wa ni gbogbo ayika ibi tiṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ, lati pese aabo, ati lati ṣediwọ fawọn janduku ti wọn le fẹẹ ṣakọlu si ọkọ BRT tabi ṣe awọn ero rẹpẹtẹ naa ni ṣuta.
Ko ti i ṣee ṣe fun Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko lati fesi si ipe wa lori iṣẹlẹ tii.