Taofeek Surdiq, Ado Ekiti
Ago ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti de adiẹ awọn ajinigbe to sọ igbo Kajọla, nipinlẹ Ekiti, di ibuba wọn, ti wọn si maa n ko awọn eeyan ti wọn ba ti ji gbe sibẹ. Wọn fibọn mu meji balẹ ninu wọn, ọwọ si tẹ awọn mẹta, Usman Dahiru, Kabiru Abubakar ati Hamidu Lawal, wọn ti wa lahaamọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, ti wọn ti n ṣalaye ohun to gbe wọn dedii iṣẹ buruku naa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, DSP Sunday Abutu, to fọrọ yii lede ninu atẹjade kan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila yii, sọ pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu yii, lawọn ṣaṣeyọri ọhun.
O lo ti pẹ tawọn ọtẹlẹmuyẹ ti n fimu finlẹ, ti wọn n ṣewadii lori iṣẹ oro tawọn kọlọransi ẹda to n jiiyan gbe ninu igbo naa n ṣe, iwadii naa lo ṣamọna bi ikọ ọlọpaa ayara-bii-aṣa, Rapid Response Squad (RRS) Ekiti ṣe lọọ gbe’ja ka wọn mọ’nu igbo naa, wọn yi igbo ọba Kajọla Forest Reserve, to wa niluu Ado-Ekiti naa po, lati fi pampẹ ofin gbe wọn.
Amọ oju bọrọ kọ la fi i gbọmọ lọwọ ekurọ o, awọn amookunṣika ẹda yii naa ba awọn ọlọpaa fija pẹẹta, wọn gboju agan si wọn, nibọn ba bẹrẹ si i pe ibọn ran niṣẹ, tọtun-un tosi si dana ibọn ya ara wọn.
Abutu ni, nigbẹyin, inu awọn dun pe ko sẹni to ba ogun naa rin ninu awọn agbofinro ọhun, ọwọ awọn ọlọpaa ro ju tawọn atilaawi yii lọ. O lawọn fibọn gbẹmi lẹnu meji ninu wọn, awọn mu mẹta looyẹ, ọpọ ninu awọn ajinigbe naa ṣiyan wọn ko duro gbọbẹ nigba ti wọn ri i pe ija naa kọja wẹrẹwẹrẹ. Pupọ ninu awọn to sa lọ ọhun ni wọn ti fara gbọta loriṣiiriṣii.
Lara awọn irinṣẹ ika tawọn ajinigbe naa n lo, eyi tawọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn ni ibọn AK-47 meji, katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin mẹtadinlọgbọn, katiriiji ọta ibọn ti wọn ti yin meje, foonu Tecno kan atawọn aṣọ ṣọja ti wọn fi n ṣiṣẹ laabi wọn.
Kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti, CP Moronkeji O. Adeṣina, ti gboṣuba fawọn ọmọọṣẹ rẹ fun igbesẹ akin ati aṣeyọri yii. O ni kawọn ajinigbe to sa lọ naa tete tuuba, tori ẹgbẹrun saamu wọn o le sa mọ Ọlọrun lọwọ, awọn ṣi n tọpasẹ wọn, awọn si maa mu wọn dandan.
O waa ṣekilọ fawọn ọdaran yooku pe ki wọn tete wabi gba, ki wọn fi ipinlẹ Ekiti silẹ, tori igbesẹ tuntun tawọn bẹrẹ lati maa gbeja lọọ ka wọn mọ ibuba wọn yii ko ni i duro, awọn maa tẹsiwaju lori ẹ kawọn eeyan ipinlẹ Ekiti le ni ifọkanbalẹ ati aabo to muna doko.