Ọlọpaa to yinbọn pa Bọlanle Raheem lọjọ ọdun Keresi loun ko jẹbi pẹlu alaye

Monisọla Saka

ASP Drambi Vandi, ọga ọlọpaa tileeṣẹ ọlọpaa ilẹ yii fofin de lẹyin to pa obinrin agbẹjọro ilu Eko kan, Bọlanle Raheem, lọjọ ọdun Keresi, ti bẹbẹ nile-ẹjọ pe oun ko jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun.

Drambi ti wọn fẹsun ipaniyan kan niwaju ile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko, to wa ni Tafawa Balewa Square, ipinlẹ Eko, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, niwaju Onidaajọ Ibironkẹ Harrison, rawọ ẹbẹ si kootu ọhun pe oun ko jebi. Lojuna ati ṣe ojuṣe wọn fun ọkan ninu ọmọ ẹgbẹ wọn to jade laye lojiji yii, ati lati pe fun idajọ ododo, ẹgbẹ awọn lọọya nilẹ yii, Nigerian Bar Association, (NBA), eyi ti Aarẹ wọn nilẹ Naijiria, Yakubu Maikyau (SAN), ati alaga ẹgbẹ naa ẹka ti ipinlẹ Eko, Ikechukwu Uwanna, ṣaaju fun, to fi mọ awọn oloye ẹgbẹ mi-in ni wọn wa nikalẹ lasiko igbẹjọ naa lati maa fọkan ba bi ẹjọ ọhun ṣe n lọ lọ.

Lẹyin ti wọn ka iwe ẹsun naa si i leti ni Vandi bẹbẹ pe oun o jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun.

Ka ranti pe, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun to kọja yii, ni Vandi, agbofinro to n ṣiṣẹ ni teṣan ọlọpaa Ajiwẹ, lagbegbe Ajah, yinbọn pa Bọlanle Raheem, obinrin agbẹjọro kan to tun wa ninu oyun oṣu meje lasiko naa, lagbegbe abẹ biriiji Ajah, nipinlẹ Eko, lasiko tobinrin ọhun atawọn ẹbi ẹ n dari bọ wa sile lati ṣọọṣi ti wọn lọ lọjọ ọdun Keresi.

Iku obinrin lọọya yii lo ti fa oriṣiiriṣii ariwo latọdọ awọn eeyan ati lajọlajọ lorilẹ-ede yii, pẹlu bi wọn ṣe n bu ẹnu atẹ lu iwa ọdaju, ika ati ipaniyan lai nidii kan pato, ti wọn lo win awọn ọlọpaa si. Fun ọpọlọpọ ọjọ ni wọn si fi n sọrọ yii, agaga lori ẹrọ ayelujara. Awọn iru iwa bayii naa ni wọn lo kun idi tawọn ọdọ fi ṣe iwọde ENDSARS lọdun 2020.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Kejila, ọdun to kọja yii, nijọba ipinlẹ Eko ti kọkọ fi panpẹ ofin gbe Vandi, ti wọn si fẹsun ipaniyan kan an lasiko to duro niwaju Onidaajọ C. A. Adebayọ, lọjọ keji ọjọ tileeṣẹ ọlọpaa buwọ lu iwe ti wọn fi fofin de e ninu iṣẹ agbofinro. Eyi waye lẹyin ti ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ yii, Usman Baba, pa a laṣẹ pe ki wọn ṣe bẹẹ.

Latigba naa ni wọn ti fi i si ahamọ ọgba ẹwọn to wa n’Ikoyi, nipinlẹ Eko, titi digba ti ẹjọ yoo fi pari.

Leave a Reply