Faith Adebọla, Eko
Loootọ ni wọn ni agbefọba ki i jẹbi, ṣugbọn ọrọ ko ti pesi jẹ fun ọga ọlọpaa ti wọn porukọ ẹ ni ASP Babatunde Adebayọ yii, ibi ti ọkunrin naa ti n fa igbo pẹlu aṣọ ijọba lọrun ẹ ni wọn ka a mọ, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe e.
Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko ṣe sọ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE, DSP Benjamin Hundeyin sọ pe agbegbe Ijọra niṣẹlẹ naa ti waye, o ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Ṣogunlẹ ni agbofinro to rufin yii n ba ṣiṣẹ.
Fọto kan lo ṣakoba fun Babatunde, fọto naa lo taṣiiri ẹ, niṣe lo jokoo sori aga ifẹyinti kan lọsan-an ọjọ naa, o fi ibọn ọwọ rẹ ha itan, eegbogi oloro ti wọn n pe ni igbo lo we mọ’ka lọwọ ọtun rẹ, lo ba n fa kinni naa sagbari ni tiẹ, lai fura pe awọn kan ti n kamẹra rẹ bo ṣe n lufin.
Laarin iṣẹju diẹ to ṣe kinni naa tan, fọto iwa palapala to hu naa ti balẹ sori ẹrọ ayelujara, lawọn eeyan ba n ta a latare, titi ti fọto naa fi de ọfiisi kọmiṣanna ọlọpaa Eko, CP Abiọdun Alabi, wọn ni ko wo ọkan lara awọn ọmọọṣẹ ẹ to n fa’gbo.
Kia ni Alabi ti ni ki wọn ṣewadii ẹni to jẹ, ajere ọrọ naa si ṣi mọ Babatunde lori, ni wọn ba mu un sahaamọ wọn.
Wọn ni Alabi ti paṣẹ pe ki agbofinro to sọra ẹ di afurasi ọdaran yii bẹrẹ si i kawọ pọnyin rojọ ni ibamu pẹlu ilana ileeṣẹ ọlọpaa, fun ipele ipo to wa lẹnu iṣẹ naa.
Alabi ni sẹria to tọ siru ẹni to ba hu iru iwa aitọ yii lawọn maa da fun un, lati jẹ arikọgbọn fawọn mi-in. O loun o ni i daṣọ bo agbofinro eyikeyii to ba lufin lori.