Ọlọpaa yinbọn pa oṣiṣẹ ajọ eleto idibo, awọn agunbanirọ fara pa yanna yanna

Jọkẹ AmỌri

Ajọ eleto idibo ilẹ wa ti padanu ọkan ninu awọn oṣiṣẹ wọn pẹlu bi ọlọpaa kan ṣe yinbọn pa a lasiko ti wọn n ko awọn ohun eelo eto idibo lọ si ibi ti wọn ti fẹẹ dibo aarẹ ni ijọba ibilẹ Ukwani, nipinlẹ Delta. Bakan naa lawọn agunbanirọ ti wọn jọ wa ninu mọto naa ṣeṣe yannayanna.

Kọmiṣanna fun ajọ eleto idibo nipinlẹ Delta, Monday Udoh-Tom ti fidi rẹ mulẹ pe ọkan ninu awọn ọlọpaa to maa n duro si oju ọna lo yinbọn pa ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ajọ eleto yii.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa niluu Asaba, Udoh-Tom ṣalaye pe inu bọọsi ni awọn oṣiṣẹ eleto idibo naa wa, wọn ko si jinna si ibi ti eti idibo aarẹ ti fẹẹ waye.

O ni ọlọpaa yii yinbọn mọ ọkọ bọọsi to n gbe wọn lọ si ibudo idibo yii nitori pe dẹrẹba bọọsi akero to n gbe wọn lọ naa ko duro nigba ti awọn ọlọpaa da a duro nibi ti wọn ti n da awọn ọkọ duro fun ayẹwo.

O ni awọn agunbanirọ ti wọn ṣeṣe yii ti n gba itọju bayii nileewosan kan ti ko darukọ.

 

Leave a Reply