Olori Alaafin Ọyọ ṣọjọọbi, o tun ṣile olowo nla

Jọkẹ Amọri

Titi di asiko yii ni ẹbi, ara, ọrẹ ati ojulumọ ṣi n ki ọkan ninu awọn Olori Ọba Adeyẹmi to ti waja, Badirat, ku oriire. Eyi ko sẹyin ayẹyẹ onibeji ti ọbinrin naa ṣe, bo tilẹ jẹ pe ko pariwo rẹ fun ẹnikẹni.

Ọjọ kẹta, oṣu Kọkanla yii, ni Olori apọnbeporẹ naa n sami ayẹyẹ ọjọọbi rẹ, o tun le ọdun kan si i loke eepẹ. Ara ọtọ to wa ninu ọjọọbi ti ọdun yii ni afihan ile tuntun to sẹṣẹ kọ to ṣe.

Olori Badirat to jẹ ọmọ ọkan ninu awọn afọbajẹ ilu Oyọ, Alapinni,  to ṣalaisi laipẹ yii ko pariwo ile to ṣẹṣẹ kọ naa rara, awọn ti wọn sun mọ ọn ti wọn mọ bo ṣe n lọ nikan lo mọ.

Ṣugbọn ni kete to gbe aworan ara rẹ ati ile tuntun to duro reterete to ṣẹṣẹ kọ naa sori ikanni Instagraamu rẹ, to si kọ ọ sibẹ bayii pe ‘Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun’. lawọn eeyan ti n ki i ku oriire, ti wọn si n ṣadura fun un pe ile naa ko ni i jẹ akọ gbẹyin fun un.

Ọkan ninu awọn to ki Olori naa ku oriire lori Instagraamu rẹ ni ẹni kan to pe ara ẹ ni wumibello. O ki i pe ‘Ku oriire ọjọọbi o, ọmọ mi Olori ọba. Ajọkẹ, ku oriire ile tuntun to o ṣẹṣẹ kọ. Ọkọ mi Ajọkẹ, ko ni i jẹ opin oore ninu aye rẹ. Igbega lọpọlọpọ, ẹmi gigun ati alaafia ni wa a fi maa lo ile aye rẹ’.

Bẹẹ ni ọpọlọpọ awọn ololufẹ rẹ ti n rọjo adura le e lori.

Tẹ o ba gbagbe, Olori ti wọn n pe ni Queen Ọla yii jẹ ọkan ninu awọn aayo Ọba Adeyẹmi ko too di pe ede aiyede kan ṣẹlẹ laarin wọn, ti Olori yii si ko jade laafin. Latigba naa ni Olori yii ti ṣi ṣọọbu to n ta awọn aṣọ loriṣiiriṣii. Bo ṣe ni ṣọọbu si Ikẹja lo ni si Lẹkki, nibi tawọn eeyan nla nla ti wa n ba a ra awọn ohun to n ta.

Leave a Reply