A-gbọ sọgba nu ni iku olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti, Funminiyi Afuyẹ ṣi n jẹ fun gbogbo eeyan titi di ba a ṣe n sọ yii. Awọn mi-in ko tiẹ ti i gbagbọ rara pe ọkunrin naa ti tẹri gbaṣọ, wọn ni irọ to jinna soootọ ni.
Eyi ko sẹyin bo ṣe jẹ pe aṣofin yii ko ṣe aisan kankan tẹlẹ, koda, wọn ni ohun ati Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ekiti, Abiọdun Oyebanji ni wọn jọ jadee, laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọkọkandinlogun, oṣu yii, ti wọn jọ ṣayẹwo si awọn oju ọna to ti bajẹ nipinlẹ Ekiti lagbegbe Baṣiri.
Yatọ si eyi, ọkunrin naa n mura igbeyawo ọmọ rẹ ọkunrin to yẹ ko waye ni Satide, opin ọsẹ ta a wa yii, eyi ti gbogbo eto si ti n lọ ni pẹrẹu lati mu ki igbeyawo naa dun, ko ni arinrin. Aṣofin kan ti ko fẹ ka darukọ oun ṣalaye fun akọroyin wa pe ọkan ọkunrin naa lo daṣẹ silẹ lojiji, to si ṣubu lulẹ, oju-ẹsẹ naa ni wọn si ṣugbaa rẹ, ti wọn gbe e lọ si ileewosan. Gbogbo ọgbọn ni awọn oniṣegun oyinbo yii ta lati ra ẹmi ọkunrin yii pada, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, akukọ ti kọ lẹyin ọmọkunrin, ko pada ji saye, oku rẹ ni wọn fi silẹ si ọsibitu ti wọn gbe e lọ.
ALAROYE gbọ pe ọkunrin naa wa nibi isin Onigbagbọ ati ti Musulumi ti wọn ṣe fun gomina to ṣẹṣẹ gba ipo l’Ekiti, gbogbo awọn ti wọn si ri i laaarọ ọjọ Wẹsidee yii lọrọ naa n ṣe ni haa-in, wọn ko le gba eti wọn gbọ rara.
Ọpọ awọn eeyan ni wọn ṣapejuwe ọkunrin naa gẹgẹ bii oniwa pẹlẹ, ẹni to fẹran alaafia, to si jẹ aṣoju rere.
Ilu Ikẹrẹ-Ekiti ni wọn ti bi Afuyẹ, to lo ọdun mẹrindinlaaadọta loke eepe ko too jade laye ọhun.
O ti figba kan jẹ kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ naa.
Akọwe iroyin fun gomina Ekiti, Yinka Oyebọde fidi iṣẹlẹ iku ásofin Ekiti naa mulẹ fun akọroyin wa.