Ọlawale Ajao, Ibadan
Abẹnugan ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Ọnarebu Debọ Ogundoyin, ti fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ko ṣiṣẹ idagbasoke si agbegbe Ibarapa, nipinlẹ ọhun.
Ṣaaju asiko yii lawọn ara agbegbe Oke-Ogun, Ibarapa ati Ogbomọṣọ, ti ni ikunsinu si Gomina Ṣeyi Makinde nitori wọn gba pe ilu Ibadan nikan lo n ṣiṣẹ idagbasoke ilu si, ko fi bẹẹ ṣe nnkan si awọn ilu to wa lagbegbe awọn.
Ọrọ ti Ọnarebu Ogundoyin sọ yii lo fidi awijare awọn ara Ibarapa mulẹ pe loootọ nijọba Makinde ko ri tiwọn ro lagbegbe naa.
Ninu fidio kan to n rin kaakiri ori ẹrọ ayelujara lọwọlọwọ lọkunrin ọmọ bibi ilu Eruwa, lagbegbe Ibarapa yii, ti fi Ọlọrun bura fawọn araalu ẹ pe gbogbo awọn ọna ti wọn ti ṣe lagbegbe Ibarapa laarin asiko ti Makinde bẹrẹ ijọba yii, oun funra oun loun ṣe e pẹlu owo ọwọ ara oun, ki i ṣe Makinde rara, nitori gomina naa ko ti i fọwọ si owo to yẹ ki wọn fi ṣe awọn iṣẹ to yẹ ki ijọba ṣe sagbegbe naa.
Pẹlu bi Ọnarebu Ogundoyin ṣe jẹ olori ẹka awọn aṣofin ninu ijọba Gomina Makinde, ti awọn mejeeji si tun jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP) kan naa, afaimọ ni nnkan ko ni i yiwọ fun gomina yii ninu idibo to n bọ yii pẹlu ọrọ ti ọkunrin ara Eruwa lagbegbe Ibarapa sọ fawọn eeyan rẹ ọhun.