Jọkẹ Amọri
Olori ijọba fidi-hẹ lorileede wa nigba kan, Ernest Shonẹkan ti jade laye lẹni ọdun marundinlaaadọrun.
Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe ileewosan aladaani kan ti wọn n pe ni Evercare Hospital, to wa ni Lekki, niluu Eko ni baba naa dakẹ si.
Baba yii lo gbajọba lẹyin ti Ọgagun Ibrahim Babangida fipo naa silẹ lẹyin to fagi le abajade esi idibo to yẹ ko gbe Oloye Kaṣimawo Abiọla wọle lọdun 1993.
Oun lo ṣejọba yii lati ọjọ kẹrindinlọgbọ, oṣu kẹjọ, titi di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 1993, ti Abacha doju ijọba naa de, to si pada di aarẹ ologun ilẹ wa.