Olori Ọpẹyẹmi diyawo laafin Ọọni

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹsẹ ko gbero laafin Ọọni Ileefẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un yii, nibi ti ayẹyẹ iwẹjẹ-wẹmu ti waye lati ki olori kẹfa, Elizabeth ỌpẹOluwa Akinmuda, kaabọ saafin.

Ayẹyẹ naa bẹrẹ nigba ti awọn mọlẹbi kabiesi, ati meji lara awọn olori, Olori Mariam ati Olori Ademiluyi fi torin tilu ki ỌpẹOluwa kaabọ saafin.

Lẹyin naa ni wọn ṣe gbogbo etutu to yẹ lati fi gba iyawo olori alade gbogbo naa sinu aafin fun un.

Awọn Ẹmẹsẹ Ọọni ni wọn ṣaaju rẹ lọ sidi odo Yemoolu (Yemolu well) lati ṣiṣẹ rẹ akọko gegẹ bii Olori Ọọni, wọn ṣalaye fun un nipa pataki odo naa.

Lẹyin eyi ni wọn sin in lọ si ile Ọọni, nibi ti awọn oloye agba niluu Ifẹ ati awọn Iyalode ti rọjo adura le e lori, ko too di pe baba rẹ fa a le iyawo to dagba ju lọ nidile Ogunwusi, Olori Margret Ogunwusi, lọwọ.

Nigba ti wọn ṣe gbogbo eleyii tan ni iyawo ọsingin lọọ jokoo lẹgbẹẹ ọkọ rẹ, ti wọn si n ba awọn etutu to ku lọ titi di aago mẹwaa alẹ ti wọn mu un lọ sinu ile ti yoo maa gbe.

Aarọ ọjọ Satide naa lawọn eeyan nla nla lawujọ, to fi mọ awọn mọlẹbi kabiesi ati ti olori tuntun naa ni wọn pe jọ si Ẹnuwa, nibi ti wọn ti ṣeto idupẹ igbeyawo naa.

Lara awọn ti wọn wa nibẹ ni Ọlọta ti Ọta Awori, Ọba Adeyẹmi Abdulkabir Ọbalanlege, aṣoju Dokita Goodluck Jonathan, nigba ti SookoLaẹkun ti Ifẹ si dari gige akara oyinbo.

Ọmọọbabinrin ilẹ Awori ni Olori Elizabeth Akinmuda, agboole Ajibode, ni Ọta, nipinlẹ Ogun, lo ti wa. O wa lara awọn olori mẹfa ti Ọọni Ogunwusi fẹ lọdun 2022, wọn kan ṣẹṣẹ sọ ọrọ ọhun di tootọ lọsẹ yii ni.

Leave a Reply