Faith Adebọla
Gbajugbaju onkọrin Juju nni, Dayọ Kujọrẹ, tawọn eeyan mọ si Wonder Dayọ, ti doloogbe.
Iyawo oloogbe naa lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu ki-in-ni yii.
Ko ti i sẹni to le sọ pato ohun to ṣokunfa iku ojiji yii.
Ilu mọ-ọn-ka olorin juju yii gbajumọ fun awo orin to pe akọle ẹ ni ‘Sọkọ’, ‘Sọkọ Extra’ ati awọn orin aladun mi-in to gbe jade.
Ọpọ ọdun lọmọ bibi ilu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, yii fi wa lorileede Amẹrika.