Monisọla Saka
Adari ijọ Ridiimu, The Redeemed Christian Church of God (RCCG), Pasitọ Adeboye, ti kọ ominu si eto aabo to mẹhẹ ati ipakupa ti wọn n paayan nilẹ Hausa, pataki ju lọ nipinlẹ Kaduna. Iranṣẹ Ọlọrun naa ni awọn iṣẹlẹ naa, ati bo ṣe jẹ pe ojoojumọ ni gbese ti ilẹ wa n jẹ n pọ si i jẹ ohun to maa n fun oun ni ironu gbogbo igba.
Adeboye sọrọ yii lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lasiko isin idupẹ oṣu Kẹrin, ọdun. Bakan naa ni iranṣẹ Ọlọrun yii sọ pe ko ti i da oun loju pe eto idibo maa waye lọdun 2023. O ni Ọlọrun ko ti i fi han oun.
‘‘Bi mo ṣe n sọrọ lọwọ yii, ko da mi loju boya eto idibo yoo waye ni Naijiria, mo sọ bẹẹ nitori pe Ọlọrun ko ti i ba mi sọrọ lori rẹ.”
Pasitọ Adeboye fi kun un pe rogbodiyan ati aifẹsẹmulẹ eto aabo ni Naijiria, ikọlu awọn agbebọn, bibẹ ọpa epo ati ipaniyan loriṣiiriṣii n jẹ ẹdun ọkan foun.
“O o le rin irinajo ori ilẹ bii ka wọ mọto, wọn le ṣe ikọlu si ni tabi ki wọn ji ni gbe. Eeyan o tun le wọ ọkọ reluwee, wọn le ṣe ikọlu fun ni, ko si ibi ti aabo to gbopọn wa. Lonii, Kaduna ni, ta lo m’ọbi to tun kan?
“Fun idi eyi, niṣe ni mo maa n rẹrin-in ti awọn eeyan kan ba n sọrọ nipa eto idibo 2023, nitori emi gan-an alara o ti i mọ boya eto idibo yoo waye. Ẹ ma sọ pe Pasitọ Adeboye sọ pe eto idibo ko ni i waye ni ọdun to n bọ o, ohun ti mo sọ kọ niyẹn o, mo ni n o ti i mọ ni. N o ti i mọ nitori pe Baba mi loke ko ti i ba mi sọrọ nipa rẹ rara.
Lasiko eto idibo to kọja, ti ọdun 2019, mo ti mọ pe eto idibo yoo waye lati oṣu kẹjọ, ọdun 2018, nitori Ọlọrun ti sọ fun mi. Fun idi eyi, ko ti i pẹ ju fun Ọlọrun lati sọrọ nipa ọdun 2023, ṣugbọn ni bayii, ko ti i sọ nnkan kan nipa rẹ.
Pasitọ Adeboye tun wẹ ara rẹ mọ ninu awuyewuye pe o n ṣojuṣaaju fn awọn oloṣelu, ati pe ijọ Ridiimu n ṣegbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu kan. O ni, “Mo ti sọ ọ tẹlẹ ri, n o si tun tun un sọ, emi ki i ṣe oloṣelu, n ko si le jẹ oloṣelu laelae. Pasitọ ni mi, ohun ti Ọlọrun pe mi fun niyẹn”. Ẹ jọwọ, ẹ jẹ ki n gbaju mọ iṣẹ mi, iṣẹ mi ni lati jẹ pasitọ, lati gbadura fun yin, lati gbadura fun awọn orilẹ-ede ati paapaa Naijiria.
Adeboye ni ko ni i bojumu, inu awọn ọmọ ijọ Ridiimu miiran ti wọn wa ninu ẹgbẹ oṣelu mi-in yatọ si APC ko si ni i dun, nigba ti ohun ba n ṣojuṣaaju, tabi ti oun n ṣegbe lẹyin ẹni kan. O ni, “Ninu ijọ Ridiimu, gbogbo ẹgbẹ oṣelu ni wọn ni aṣoju ti ki i ṣe kekere; APC, PDP, APGA, Labour ati awọn ẹgbẹ oṣelu miiran ti a o tiẹ morukọ wọn. Bẹẹ, n o ti i sọ iru ẹgbẹ oṣelu ti ẹ oo dibo fun fun yin ri boya ni kọrọ ni o tabi gbangba. Fun idi eyi, iwa ko tọ ni yoo jẹ ti n ba sọ fun yin pe kẹ ẹ ṣegbe fun ẹgbẹ oṣelu kan”.
Ọrọ ti Adeboye sọ nipa pe ko ni nnkan kan an sẹ pẹlu oṣelu yii le ma sẹyin atẹjade kan ti ijọ Ridiimu gbe jade laipẹ yii nipa ẹka ti yoo maa ri si igbimọ iṣelu ati iṣejọba, iyẹn ‘Directorate of Politics and Governance’ ninu ṣọọṣi naa.
Ṣe bi wọn ti kede erongba lati ni ẹka yii ni awọn kan ti n pariwo pe o ṣee ṣe ko jẹ nitori ọkan ninu awọn ọmọ ijọ naa to tun jẹ Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ni wọn tori ẹ da ẹka yii silẹ.
Ọkunrin naa ni awuyewuye ti n lọ lori ẹ pe o fẹẹ dupo aarẹ ilẹ yii, ti Buhari ba pari iṣejọba rẹ, ati pe eto ijọ awọn Ridiimu yii wa lati ṣatilẹyin fun ọmọ ijọ wọn, iyẹn, Yẹmi Ọṣinbajo, lakooko eto idibo.
Iranṣẹ Ọlọrun naa waa rọ awọn ẹlẹsin Kristẹni lati kopa ninu eto idibo to n bọ. O ni, “Ọmọ Naijiria ni yin ko too di pe ẹ di ọmọlẹyin Kristi. Ẹ ni ojuṣe si orilẹ-ede yin lati forukọ silẹ, ati lati dibo. Ẹ lẹtọọ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu to ba wu yin ni ẹsẹkuku, ẹ ẹ kan le jokoo silẹ, ki ẹ kawọ bọtan, ki ẹ kọ lati dibo, kẹ ẹ tun waa bẹrẹ si i maa ṣaroye nipa ijọba. Nigba ti wọn ba n dibo tẹ ẹ jokoo sile, tẹ ẹ forukọ silẹ, tẹ ẹ ko dibo, awọn ti wọn ba jade dibo ijọba ibilẹ, ipinlẹ tabi ti aarẹ naa ni yoo yan olori fun yin nigba tẹ ẹ kọ lati ṣe nnkan kan”.
“Ẹ gbọdọ forukọ silẹ , ẹ gbọdọ dibo, ẹ si gbọdọ jokoo sibẹ lẹyin ti ẹ ba dibo tan kẹ ẹ ri i daju pe wọn ka a, ki ẹ si kiyesi ẹni ti wọn ba sọ pe o wọle. Ẹ gbọdọ ri i daju pe ko si magomago ninu eto idibo Naijiria mọ.