Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Niṣe ni ọrọ ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Olufẹmi Opẹyẹmi, da bii ole to gbe kakaki ọba, nibo ni yoo ti fọn ọn, pẹlu bi ọkan rẹ ko ṣe balẹ lẹyin to lọ si ori oke adura kan ti wọn n pe ni ori oke Ayọ Babalọla, Christ Apostolic Church ( CAC), to wa ni Ikeji-Arakeji, nipinlẹ Ọṣun, to si lọọ palẹ owo ọrẹ ti wọn da sibẹ mọ, lo ba gbe e sa lọ.
Ṣugbọn ẹri ọkan ko jẹ ki ọmọkunrin naa gbadun lẹyin to ko owo to fẹrẹ to miliọnu kan Naira naa tan. Lo ba lọọ fi ara rẹ han fawọn ọlọpaa, o ni oun fẹẹ da owo ti oun ji pada, nitori oun ko ni alaafia rara latigba toun ti ji i.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti lo ṣe afihan ogbologboo ole naa lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.
Ọmọ bibi Iropora-Ekiti, ni Olufẹmi, o si ti figba kan ṣiṣẹ ẹṣọ alaabo lori oke adura naa ri. Niṣe lo kan lọ sori oke naa, ti ko si bẹru boya ẹnikẹni n wo oun tabi wọn maa ko oun loju pe nibo ni oun n gbe owo naa lọ. Bo ṣe bọ sori pẹpẹ naa lo lọọ gbe apo nla kan ti wọn maa n da owo ọpẹ si lori oke ọhun, ti ko si si ẹnikankan to da a duro. Lẹyin eyi lo ta mọ ọkada to gbe wa, lo ba sa lọ.
Nigba tawọn ọlọpaa n ṣafihan ọmọdekunrin yii ni ọfiisi wọn, Alukoro wọn, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣalaye pe ọwọ awọn agbofinro tẹ Opẹyẹmi n’Igbara-Odo, lẹyin to gbe owo ọpẹ naa kuro lori oke adura ọhun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Lọjọ kẹrindinlogun, oṣun Kẹsan-an, ọdun yii, ni deede aago mẹrin aabọ irọlẹ ni awọn ọlọpaa da ọkunrin yii duro lori ọkada, ti wọn si ba apo nla to di ọpọlọpọ owo sinu rẹ. Ni wọn ba beere ibi to ti ri aduru owo bẹẹ. Ọpẹyẹmi ṣalaye fawọn agbofinro pe owo ọpẹ ati owo ọrẹ ni owo naa, ati pe ori oke oke adura Ayọ Babalọla to wa ni Arakeji loun ti ji i.
“Nigba ti wọn fi ọrọ wa a lẹnu wo, ọdaran naa jẹwọ pe oun wa lati Iropora-Ekiti si ori oke naa lati waa ji owo ti awọn to waa gbadura da sibẹ to to bii miliọnu kan Naira.
“Ọdaran naa ti figba kan jẹ ẹṣọ alaabo lori oke yii ko too kọwe si awọn oludari ibẹ pe oun ko ṣiṣẹ na mọ.
Nigba ti awọn akọroyin n fi ọrọ wa a naa lẹnu wo, o ṣalaye pe ọdun mẹta gbako ni oun fi ṣiṣẹ gẹgẹ bii ẹṣọ lori oke naa, ti oun si fi gbogbo igba naa di atunbi, ṣugbọn oun ko mọ oun to fa a ti oun fi tun pada sinu ẹṣẹ.
O ṣalaye pe ni kete ti oun ji owo naa tan ni ẹmi Ọlọrun fọwọ kan ọkan oun, ti oun si funra oun lọọ sọ fun awọn ọlọpaa to wa loju ọna pe oun ti lọọ ji owo ọpẹ ati ọrẹ lori oke Arakeji.
Ọdaran yii ni latigba naa loun ti wa lakata awọn ọlọpaa, aawẹ ati adura loun si n gba latigba naa ki oun le ri idariji gba latọdọ Ọlọrun.
Nigba ti awọn ọlọpaa gbe owo to ji ọhun, eyi to ko sinu apo siwaju rẹ, o ni inu abọ nla kan ni owo ọhun maa n wa lori oke naa, niṣe ni oun si gbe e, ti oun da a sinu apo, loun ba gbe e kuro nibẹ ko too di pe ẹri ọkan ko jẹ ki oun gbadun, ti oun si lọọ ṣalaye fawọn ọlọpaa pe oun fẹẹ da owo naa pada, nitori ẹri ọkan ko jẹ ki oun gbadun.