Faith Adebọla
Orin, “ẹ ba mi jijo ọpẹ o” ti gba ẹnu mama agbalagba ẹni aadọrin ọdun kan ti wọn porukọ rẹ ni Safina Namukwaya, latari bi Ọlọrun ṣe jẹwọ agbara rẹ laye obinrin naa, to bi ọmọ fungba akọkọ lẹni aadọrin ọdun, ibeji lo si fi ọmọ naa bi, ọkunrin kan ati obinrin kan.
Aarin ọsẹ yii, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla yii, niṣẹlẹ amọkanyọ naa waye niluu Kampala, ti i ṣe olu-ilu orileede Uganda.
Bo tilẹ jẹ pe pẹlu iranlọwọ imọ ẹrọ igbalode ati ilana sayẹnsi ni iloyun awọn ejirẹ ara Isokun naa fi ṣee ṣe, wọn ni iṣẹ abẹ ni wọn ṣe fun mama agbalagba yii lasiko to n rọbi ni ọsibitu Women Hospital and Fertility Centre, to wa niluu naa, to fi bi awọn ọmọ ọhun, amọ ọpẹ ni pe ọmọ ke, iya naa fọhun nigbẹyin.
Pẹlu idunnu lawọn alaṣẹ ọsibitu naa fi gbe fọto ati fidio iya ibeji yii atawọn ọmọ rẹ soju opo Fesibuuku wọn, ti wọn si kọ ọrọ sibẹ pe:
“Bẹẹ ni o, o bi ibeji, ọkunrin kan ati obinrin kan. Aṣeyọri to fitan balẹ gidi ni.
“Ba a ṣe n kan saara si obinrin yii fun ọkan akin rẹ, ta a si n gbadura ilera fun awọn Taye-Kẹyin, ẹ ba wa yọ’’.
Mama ibeji funra ẹ naa ti sọrọ. Ninu ọrọ kan to ba awọn oniroyin sọ, o ni oriṣiiriṣii ọrọ ẹgan ati ipọnju loun fara da lasiko toun fi wa lagan. Obinrin yii ni, “mo ranti ọjọ kan ti ọmọdekunrin kan bẹrẹ si i rọjo eebu le mi lori pe ẹni egun ni mi, o ni mama mi lo fi mi gegun-un pe mi o le rọmọ bi laye.
O tun ni nigba toun loyun paapaa, awọn ọkunrin ki i fẹẹ gbọ pe ọmọ to wa nikun oun ju ẹyọ kan lọ. Ati pe latigba toun ti wa lọsibitu yii, oun ko ti i ri ọkọ oun ko yọju.”
ALAROYE gbọ pe ilana iṣegun onimọ ijinlẹ, ti wọn n pe ni in-vitro-fertilisation, IVF, ni obinrin naa fi loyun. Niṣe ni wọn gba atọ ọkọ rẹ, ti wọn si fi imọ ẹrọ da a pọ pẹlu ẹyin mi-in, nigba ti kinni naa si ti ẹyin to le dọmọ ni wọn ba da ọlẹ yii pada sinu ikun mama ẹni aadọrin ọdun yii, titi toṣu mẹsan-an fi pe, to si fi ọmọ ọhun bi ibeji lanti-lanti.