Bi mo ṣe fẹẹ jade nile ni mo pade Sẹki, mo fẹẹ maa sọ pe ṣe ko si nnkan laaarọ kutu, o ma ṣe ajimuna, lo waa sọ fun mi pe itosi wa loun sun nile ọkọ oun, awọn ti gbe Iya Tọmiwa pada lanaa, ara ẹ ti ya daadaa, pe ki n le waa ki i loun ṣe tete waa sọ ki n too jade. Mo waa ni ṣe oun naa ti ri i bayii, mo fẹẹ tete de sọọbu nitori awọn eeyan to n bọ lati banki, nitori ọrọ ile yẹn. Kia lo ni ki n tete maa lọ, o ni ki n ma duro rara, nitori oun gan-an n bọ waa ba mi nibẹ bayii. Mo ni ko ma wa, ti mo ba de ni o waa ṣalaye ohun ti mo ba ba bọ.
Nigba naa ni inu ẹ too dun, lo ba tun di mi lọwọ mu ni gbangba ita nibẹ, lo ni, ‘Iya mi, ohun to wa lọkan yin yii, Ọlọrun maa ṣe e fun yin, ẹ ko ni i ṣe wahala lasan lori ẹ!’ Ni mo ba ṣe amin ẹ. Bo ṣe n ṣadura yẹn, ọdọ Safu ni ọkan mi tun lọ, awọn ọmọ mejeeji yii ṣe waa jọ ara wọn bayii. Ọlọrun funra ẹ lo fi wọn kẹ mi. Ibi ti mo ti n sọ pe o ṣeun, ko tete maa lọ, ni Aunti Sikira ti jade, ni Sẹki ba ni, ‘Mọmi Eko’, orukọ to maa n pe aunti yẹn niyẹn ti inu ẹ ba dun si i, ti ko sija laarin wọn, nitori Aunti Sikira laiki ki wọn pe oun lọmọ Eko, tabi ki wọn ni oun ja si i!
‘O tiẹ daa, Ọmọ Jọ Dadi, o daa too wa sibi loni-in!’ Sẹki loun naa maa n pe ni Ọmọ-Jọ-Dadi ti ko ba ti sija kankan nilẹ tẹlẹ, ‘Iyawo ti baba ẹ fẹ maa fi ibasun pa a o! Kẹyin ọmọ ma ni emi Mọmi Eko kan lo ṣe baba yin leṣe, ọmọ to gbe wale yẹn fẹẹ ṣe e leṣe, mo dẹ n wi temi to o! To ba …’ Ibi ti emi gbọ ọrọ ẹ de niyẹn nitori mo ti ta kẹẹkẹẹ bọ sita, n ko le duro maa gbọ ọrọ rirun bẹẹ, ohun ti mo n sa fun lataarọ ree, obinrin eleṣu yii ṣaa n wa ẹni to maa ko ba. Sẹki naa mọ, o mọ pe bi iya oun ko ba ti fẹran ọrọ kan ni yoo tete maa lọ bẹẹ, ko yaa pe mi!
Ki eeyan ji laaarọ ọjọ ẹ ko jẹ ẹjọ ti yoo maa ro niyẹn. Mo yaa sare jade, ko si ti i ju aago mẹsan-an aabọ ti mo pada de ṣọọbu mi. Safu ni awọn ara banki ko ti i de, ṣugbọn mo ba a to ti n ta awọn ọja kan lọwọ ara ẹ. Ọlọrun lo tiẹ waa ni ki n wa bẹẹ, ko si Abbey, ko si Raṣida, Safu nikan lo wa ni ṣọọbu. Nibo lawọn ọmọ yii waa wa, ti ko ba waa si Safu nkọ. Nigba to taja yẹn tan lo wa n ṣalaye fun mi pe Abbey ti ya sọọbu tẹlẹ, ara ọmọ ẹ ko ya ni. ‘Haa’, ni mo ṣe. Mo ni mo n lọ sibẹ niyẹn. Lo ba ni wọn o si nile, wọn ti fi mọto ṣọja gbe e lọ, igba ti wọn n lọ lo ya yẹn, o da bii pe ọsibitu awọn ọkọ ẹ ninu baraaki awọn ṣọja ni wọn n gbe e lọ.
Oun naa ri i pe ara mi ko balẹ mọ, lo ṣaa n sọ pe ‘Iya mi ẹ ni suuru! Ṣebi mo rọmọ naa, ohun to n ṣe e ko le to bẹẹ, ko ma jẹ wọn ti loyun mi-in le e ni!’ Ohun to fi ọkan mi balẹ diẹ ko ju pe o ni ti oun ba ti n pada bọ, oun maa ya lọ. N la ba jokoo, a ko gburoo Raṣida ni tiẹ, Safu n taja ẹ lọ, n ko le fi i silẹ. Awọn ti a n reti lati banki ko wa, o si ti n lọ si bii aago mejila, mo ni bi awọn alakọwe ti maa n ṣe niyẹn nigba mi-in. Mo waa ni ko waa lọọ ra iyan ka jẹ o, nitori mo mọ pe oun naa o ti i jẹun. Ṣugbọn Safu o ṣee fara we, o le gbe e ṣulẹ bẹẹ, bi aje ba ti n wọgba!
Lo ba ni oun maa diidi wa iyan ologunfe ti mo maa n laiki yẹn lọ ni, pe oun fẹẹ ṣe iya oun lalejo loni-in to jẹ awa meji pere naa la wa ni sọọbu. Bo ṣe gbe lailọọnu pe ko jade, ti emi naa n rin bọ nita ki n le baa duro sibẹ, bi ẹnikan ṣe n paaki mọto niyẹn, mo tiẹ ro pe awọn ara banki ni tẹlẹ. Safu naa ro pe awọn ni, kia lo ti sare pada wa sile to gbe lailọọnu ati awo to n lọọ fi ra iyan silẹ, o ti ṣoju furu, to ti tun yan jade. Nigba ti awọn yẹn bọ sile la ri i pe ki i ṣe awọn ara banki, awọn Mọla kan leleyii. Ni wọn ba rin ba Safu nita, emi ti wọle.
Mo ṣaa n gbọ ti wọn n sọrọ, wọn ni emi lawọn waa ri, pe ẹnikan lo juwe ọdọ wa fawọn, wọn si ti ni ti awọn ba ri mi, ohun ti awọn ba wa maa yanju. Ni Safu ba waa sọ fun mi, ‘Iya mi, wọn lẹyin lawọn waa ri o!’ Ni mo ba jade, mo mu wọn wọle lẹyin ti mo ti ki wọn tọyaya-tọyaya tan. Ni wọn ba sọ pe lati Abuja ni awọn ti wa, wọn ni Alaaji kan lo ni ki awọn waa ba mi. Mo ni ki lorukọ ẹ, nigba ti wọn fun mi ni kaadi ẹ lo ba di Alaaji kan ti a lọọ ba ni Abuja nijọsi, emi ati Sẹki, Iyẹn ti n lọ si bii ọdun marun-un bayii o, nigba ti mo fi fẹẹ maa sọpulai wọn nibẹ.
Gbogbo eyi ti a n wi yii, Safu ti gbe omi siwaju wọn, o ko miniraasi meji tutu si i, o ko kọọpu ti i, inu awọn naa dun gan-an. Nigba naa ni mo beere ohun ti wọn ba wa gan-an. Ni wọn ba ni afi ki n gba awọn. Irẹsi lawọn n wa, o dẹ pọ gan-an ni, awọn si gbọdọ ri i laarin ọsẹ meji si mẹrin. Mo ni iyẹn ko le, ni wọn ba n rẹrin-in, mo ni ki lo de, wọn ni o le o! pe ki i ṣe ẹyọ apo kan lawọn n wa, bẹẹ ni ki i ṣe tirela kan, lakọọkọ gbara, awọn maa nilo to tirela ogun, lẹyin naa lawọn maa tun ko tirela ogun mi-in, ati ogun mi-in, iyẹn to ba jẹ mo le ba awọn wa a.
Ọkan mi n sare ṣiṣẹ bii aago ni, mo mọ pe tirela nla kan, bii ẹgbẹta apo ni yoo kun inu ẹ, ogun tirela, ẹgbẹrun mejila apo irẹsi niyẹn, ẹgbẹrun mejila lọna mẹta, iyẹn yoo si jẹ bii apo ẹgbẹrun mẹrindijlogoji, ni mo ba foyinbo sọro, mo ni bii fọọti-taosan baagi lẹ n fẹ yẹn, ni wọn ba woju ara wọn. Ki i ṣe iru oyinbo fọọti fifti bẹẹ ni n ko gbọ o, ka ṣaa dupẹ lọwọ awọn ọmọ wa, paapaa Sẹki yẹn. Niṣe lawọn mọla mejeeji woju ara wọn, wọn ni bẹẹ ni. Ni mo ba fọgbọn pe Safu, mo mọ pe o n gbọ. Mo ni eelo ni wọn n ra apo raisi bayii.
Mo kuku mọ ẹni ti mo ni, mo mọ Safu. Ẹgbẹrun marun-un lo bu le e lori hau, yatọ si iye to n ta a fawọn onibaara ẹ tẹlẹ ti mo ni o ti fi ẹgbẹrun marun-un le e lori. Owo ti a kọkọ ṣẹ gbara ti n lọ si bii miliọnu lọna ẹgbẹrun kan, niṣe ni mo si n laagun labẹ aṣọ nigba ti awọn yẹn ni ki n mu akaunti mi fawọn, ti wọn si ṣi kọmuputa kekere ti wọn gbe dani. Eyi to wa nibẹ si fi owo to to ẹẹdẹgbẹta miliọnu ranṣẹ lẹekan naa sinu banki mi. O ni ki n le fi bẹrẹ iṣẹ ni o, ti mo ba ti n ri i ni ki n maa pe awọn, awọn aa maa fi tirela ranṣẹ lẹsẹkẹkẹsẹ, wọn ni Alaaji to juwe emi fawọn ti sọ pe ko sewu, eeyan daadaa ni mi.
Tit ti a fi sin wọn wọ mọto, niṣe ni mo n laagun. Nigba ti a pada wọle, ooyi fẹẹ kọ mi, Safu lo kunlẹ to bu mi so, toun naa n pariwo, ‘Iyaa mi! Iyaami! Abẹẹ r’Ọlọrun!’ Ọrọ owo ile ti kuro ninu eleyii, owo nla gidi ti n ko ri iru ẹ ri niyi. Nibo loju ẹ wa Olodumare. Ṣugbọn nibo ni mo ti fẹẹ ri irẹsi egbẹrun lọna ogoji, n ko ro pe emi funra mi da ni ẹgbẹrun marun-un sibi kan. Ṣugbọn mo mọ pe Ọlọrun to ṣe eyi yoo ṣe eyi to ku. Awọn wo leleyii, nibo ni wọn ti waa wa, kin ni wọn fẹẹ fi irẹsi to to bayii ṣe! Haa, haa, haa ni mo n ṣe. Ọlọrun oju ẹ da!