Ọlọrun ti fun wa ni ilẹ at’ojo, ọmọ Naijiria kankan o gbọdọ sunkun ebi o – Aarẹ Buhari

Faith Adebọla

Olori orileede wa, Aarẹ Muhammadu Buhari, ti sọ pe awawi lasan lawọn to n sọrọ nipa ebi ati ọwọngogo ounjẹ nilẹ wa n ṣe, o ni ko sidii tebi fi gbọdọ pa ẹnikẹni, tori ohun ti kaluku nilo lati pese ounjẹ ti wa, Ọlorun lo si fun wa lọfẹẹ, o ni ko yẹ kẹnikan tun maa sunkun ebi mọ lasiko yii.

Buhari sọrọ yii lasiko ifọrọwanilẹwo kan to ṣe lede Hausa fun ileeṣẹ tẹlifiṣan Tambarin, to fikalẹ siluu Kano, laṣaalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjo kẹta, oṣu Kọkanla yii.

Nigba to n fesi si ibeere kan ti wọn bii lori ọwọngogo ounjẹ ati ebi to n pa araalu, paapaa latari omiyale to waye kaakiri awọn agbegbe kan lorileede yii, Buhari ni:

“Nigba ti mo gori aleefa lọdun 2015, ọkan lara eto ti mo ṣe gẹgẹ bii ilana lati pese ounjẹ lọpọ yanturu faraalu ni pe ka gbegi dina kiko ounjẹ wọlu lati oke-okun, ka si sọ ọ di ọranyan fawọn eeyan wa lati pada soko, ki wọn si maa jẹ ounjẹ ilẹ wa.

“Mo pinnu nigba naa lati fopin si kiko irẹsi wọlu, mo ni afi ka jẹ ounjẹ tawa funra wa pese, aijẹ bẹẹ, ebi aa lu wa pa.

“Mo beere pe njẹ idi kan wa fun ọmọ Naijiria kan lati kigbe ebi nigba ti Ọlọrun ti pese ilẹ ọlọraa fun wa, ti Ọlọrun si tun fi ojo jinki wa. Ẹni tebi ba n pa, ko kọja soko.”

“Loootọ, mo mọ pe asiko akunya omi lasiko yii, mo si mọ pe omiyale ti ba ọpọ ire-oko jẹ, ṣugbọn a ṣi n ta irẹsi ta a ṣe ni Naijiria, a ṣi ni ounjẹ to pọ to lati jẹ. Ṣe ki i ṣe aṣeyọri niyẹn ni?”

“A ti ri ọpọ oṣiṣẹ ti wọn fi iṣẹ ọfiisi silẹ, ti wọn kuro labẹ ẹrọ amuletutu ti wọn n gbadun lọfiisi, ti wọn si kọri soko, ọpọ wọn lo ti n kore oko rẹpẹtẹ bayii. A mọyi bi wọn ṣe n pese ounjẹ fun wa lọpọ rẹpẹtẹ.”

Bẹẹ ni Buhari sọ o.

Leave a Reply