Stephen Ajagbe, Ilọrin
Ọkan lara awọn wolii to maa n sọ asọtẹlẹ ni Woli Peter Kọlawọle Williams tijọ Christ Apostolic Church (CAC), Faith Chapel, to wa niluu Ilọrin. Ninu asọtẹlẹ rẹ ti ọdun yii lo ti ni Ọlọrun yoo mu meji ninu awọn to wa nidii iṣoro to dojukọ Naijiria kuro, ati pe oun ri ọfọ nla to ṣẹ nile ijọba apapọ l’Abuja, adura gbogbo ọmọ orilẹ-ede yii lo le da ọfọ naa duro.
O ni ohun ti ko jẹ ka ri ọna abayọ si iṣoro ọrọ-aje ati eto ilera to dẹnukọlẹ ni pe awọn eeyan ti jinna si Ọlọrun.
Woli ọhun ni iṣẹlẹ nla meji ni yoo ṣẹlẹ lọdun yii to maa mu kawọn eeyan maa wo ọdun 2020 bii ọdun to tun dara ju eyi lọ.
“Ọlọrun sọ pe oun yoo tu awọn aṣiri nla nipa ijọba to wa lori ipo yii. Ohun idọti ti wọn n gbe pamọ yoo han kedere si gbogbo araalu. O ni meji lara awọn to sọ Naijiria sinu iṣoro yoo jade laye.
“Bakan naa, Ọlọrun ni ka gbadura daadaa ki ọkan lara awọn to fẹẹ dupo aarẹ lọdun 2023 ma ku lọdun yii. O ni ka gbadura ta ko ọfọ nile ijọba apapọ.”
Woli P.K Williams fi kun un pe ọpọlọpọ ijamba ina yoo jo awọn ọja kaakiri, bẹẹ ni awọn eeyan yoo mọ-ọn-mọ dana sun ile awọn kan. O ni awọn kan yoo gbe ounjẹ to ni majele sita, ti yoo si fa iku ọpọlọpọ.
O ni awọn abami ẹranko to ri bii ọmọ, eyi to wọpọ lorilẹ-ede China ati India yoo bẹrẹ si i fara han ni Naijiria.
“Ọlọrun ni ijọba yoo di awọn eeyan lọwọ lati maa sin in, ṣugbọn oun yoo kọju ija si wọn pada. Ko daju pe alaafia yoo wa fun gbogbo agbaye nitori pe ọpọlọpọ awọn iṣẹlẹ ati ajalu nla maa waye.
“O ni ọpọlọpọ awọn ẹni mimọ to n sin oun yoo gbadura fun iku lati pada si ọdọ oun, oun yoo si gbọ adura wọn.”
O ke si awọn araalu nipinlẹ Kwara lati gbadura gidi ta ko ọfọ.
“Ọlọrun ni ka gbadura kikankikan ki gbogbo orilẹede Naijiria ma pẹjọ si Kwara lati waa ṣọfọ. O ni oun yoo ṣi ilẹkun ohun amuṣọrọ tuntun fun orilẹ-ede yii.”