Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti ke si gbogbo awọn ti wọn n sin aja lati mọ ọna ti wọn ko fi ni i maa rin kaakiri ilu mọ nitori olowo aja to ba bu eeyan jẹ yoo foju bale-ẹjọ.
Ọga agba ẹka to n ri si itọju awọn nnkan ọsin nileeṣẹ ọrọ agbẹ ati ipese ounjẹ l’Ọṣun, Dokita Abọsẹde Ọlatokun, lo ṣekilọ yii nibi akanṣe eto ọlọdọọdun lori gbigba abẹrẹ fun awọn aja.
Ọlatokun sọ pe ijọba apapọ ti pese abẹrẹ aja (anti-rabies vaccines) ẹgbẹrun mẹta ataabọ fun ipinlẹ Ọṣun.
O ni ohun tijọba fẹ ni ki awọn ti wọn n sin nnkan ọsin, paapaa, aja, wa ibi kan ti wọn yoo maa ko wọn pamọ si dipo ki wọn maa rin kaakiri inu ilu.
O ke si gbogbo awọn ọlọsin aja lati gba abẹrẹ naa fun wọn lasiko nitori ijọba ko ni i fojuure wo ẹnikẹni ti aja rẹ ba bu araalu jẹ.
Ṣaaju ni kọmiṣanna fun ọrọ agbẹ ati ipese ounjẹ, Adedayọ Adewọle, ti sọ pe erongba ijọba ni lati ri i pe ko si awọn nnkan ọsin ti wọn le ṣejamba fawọn araalu kaakiri ipinlẹ yii.
Bakan naa ni aṣoju ileeṣẹ to n ri si ọrọ ọgbin ati idagbasoke igberiko lorileede yii, Dokita Ọlaniran Alabi, ti sọ pe pẹlu abẹrẹ ajẹsara naa ati ipolongo igbadegba, wahala tawọn nnkan ọsin n da silẹ yoo dinku pupọ.