Oludamọran Aarẹ lori eto iroyin, Ajuri Ngelale, kọwe fipo silẹ

Adewale Adeoye

Ni bayii, olubadamọran Aarẹ Tinubu lori eto iroyin, Ọgbẹni Ajuri Ngelale, ti kọwe fipo silẹ bayii. Idi to ni oun ṣe gbe igbese yii ni lati le mojuto ipenija ilera kan to n koju ẹbi oun lọwọ yii.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keje, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, lo sọrọ ọhun di mimọ lori ẹrọ ayelujara rẹ kan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni, ‘Mo ti fun Olori awọn oṣiṣẹ ninu ijọba orileede yii, Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila, niwee ifiṣẹ silẹ mi, mo si ti sọ fun un idi pataki to mu mi kọwe fiṣẹ mi silẹ ninu ijọba to wa lode bayii. Ki i ṣe idunu mi rara lati fiṣẹ ti mo n ṣe yii silẹ, paapaa ju lọ lasiko yii ti orileede Naijiria nilo mi gidi gan-an, ṣugbọn mo gbọdọ ṣe bẹẹ lati gbaju mọ ọrọ ẹbi mi ni

Ẹbi ṣe pataki pupọ, ẹbi mi kan lo ni ipenija ilera lọwọ yii, mo si gbọdọ wa pẹlu rẹ. Ko rọrun rara fun mi lati gbe igbesẹ ti mo gbe yii, aimọye ọjọ lo gba mi, ti emi pẹlu awọn ẹbi mi fi jiroro lori ọrọ naa ko too di pe mo kede rẹ bayii.

Yatọ si pe ma a fipo mi gẹgẹ bii olubadamọran Aarẹ silẹ, mo tun ti kọwe fipo mi gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ igbimọ alabẹ ṣekele kan ti Aarẹ gbe kalẹ lati ri si bi oju ọjọ ṣe n lọ ‘Envoy on Climate Change’ ati ipo pataki kan ti Aarẹ Tinubu fi mi si.

Ṣa o, bi nnkan ba lọ deede gẹgẹ bi mo ṣe ro o,  o ṣi wu mi lati pada sẹnu iṣẹ mi lati sin orileede baba mi lọjọ iwaju si i.

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 to kọja yii, ni Aarẹ Tinubu yan Ajuri Ngelale sipo  gẹgẹ bii oludamọran rẹ nipa eto iroyin. Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii,  ni Tinubu tun fun un niṣẹ mi-in kun eyi to n ṣe tẹlẹ, o si wa lara ọmọ igbimọ alabẹṣekele kan to n ri sọrọ b’oju ọjọ ṣe n lọ ‘Envoy on Climate Change’.

Ko too di pe o gbaṣẹ lọwọ Aarẹ Tinubu, gbajumọ oniroyin ni, o ti figba kan ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ Tẹlifiṣan ‘African Independent Television’ (AIT), Channels Television ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Leave a Reply