Olubadan rọ ọkan ninu awọn Mọgaji ẹ loye

Ọlawale Ajao, Ibadan

Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun, ti rọ ọkan ninu awọn ijoye Ibadan, Oloye Ọlawale Ọladọja loye.

Oloye Ọladọja, to jẹ Mọgaji agboole Akinṣọla, nijọba ibilẹ Akinyẹle, nipinlẹ Ọyọ, l’Ọba Balogun rọ loye nitori ẹsun iwa buruku kan tawọn ara abule ẹ fi kan an.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun  (17), oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii, ni Mọgaji Akinṣọla fi agadagodo ti awọn ile kan pa lagbegbe to joye le lori. Njẹ ki lo de, o loun ti gba idajọ ile-ẹjọ, eyi to ṣafihan oun gẹgẹ bii lanlọọdu lori ile awọn eeyan naa, nitori ọna ti awọn olugbe inu ile wọnyi gba ra ilẹ wọn ko bofin mu.

O fẹẹ to igba (200) ile ti wọn ṣe bẹẹ ti pa lọjọ naa, eyi to mu ki ọpọ awọn lanlọọdu nibẹ sun ita mọju ọjọ keji ti i ṣe ọjọ Jimọ to kọja.

Laaarọ ọjọ keji, awọn lanlọọdu wọnyi, to fi mọ awọn ti ko ri ibi gidi sun mọju ninu wọn, atawọn ti wọn ko raaye wẹ, to jẹ omi lasan ni wọn fi bọju, ti wọn fi ṣan apa ati ẹsẹ wọn gbera, gbogbo wọn kọri saafin Olubadan lati fẹhonu han nipa iṣẹlẹ ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ bii iwa ifọwọ-ọla-gba-ni-loju naa.

Lẹsẹkẹsẹ l’Ọba Balogun pe ipade pajawiri pẹlu awọn igbimọ oludamọran rẹ. Aṣoju awọn Mọgaji, Oloye Asimiyu Adepọju Ariọri ati Mọgaji Akinṣọla, pẹlu awọn aṣoju adugbo ọhun ni wọn wa nibi ipade naa.

Nibi ipade ọhun ni wọn ti pinnu ijiya fun Mọgaji Akinṣọla, n l’Olubadan ba fofin de ọkunrin naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejidinlogun (18), oṣu Kẹjọ, ọdun yii, o ni ko yẹba diẹ na gẹgẹ bii alaṣẹ agboole wọn.

Ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin, Oluranlọwọ fun Olubadan Balogun lori eto ikede ati iroyin, Ọgbẹni Ọladele Ogunṣọla, fidi ẹ mulẹ pe ọpọlọpọ abule lo wa labẹ iṣakoso Mọgaji Akinṣọla yii, ṣugbọn awọn ti iṣẹlẹ yii kan ju ninu wọn ni aba Apọ́nmọ́dẹ̀, Lábínkúlú.

Ọgbẹni Ogunṣọla fìdi ẹ mulẹ siwaju pe ninu ipade pajawiri ọhun lawọn baalẹ meji kan ti kin awọn to fẹjọ Mọgaji ti wọn da duro yii lẹyin, wọn ni niṣe lọkunrin naa pe awọn mọra lati jọ maa gba ilẹ lọwọ awọn lanlọọdu, ṣugbọn awọn ko gba si i lẹnu.

Ninu awijare tiẹ naa niwaju Olubadan atawọn ọmọ igbimọ rẹ, Mọgaji Akinṣọla ṣalaye pe nnkan ìní idile awọn loun n ja fun, nitori pe ọna ti awọn lanlọọdu adugbo awọn gba ra ilẹ ti kaluku wọn kọle si ko tọna.

Gbogbo ọna lo sọ pe oun tọ lati fi yanju ọrọ naa ko too di pe oun pinnu lati gbe igbesẹ ti oun gbe yii lẹyin ti oun ti fọrọ ọhun to aafin Olubadan leti, ṣugbọn ti oun ko gbọ nnkan kan lati aafin latigba naa.

O ni sibẹsibẹ naa, awọn oṣiṣẹ eleto aabo loun lọọ ba

lati ba oun gba ilẹ ẹbi oun ti awọn eeyan naa ra lọna aitọ, ki i ṣe pe oun kan da igbesẹ ọhun gbe latọwọ ara oun nikan.

Nigba to n sọrọ lorukọ Ọba Balogun, Aṣipa Olubadan, Ọba Abiọdun Kọla-Daisi, sọ pe Mọgaji Akinṣọla ko tẹle ofin to de awọn Mọgaji ati baalẹ nigba tawọn fi wọn joye.

“Loootọ lọrọ yii ti wa laafin ṣugbọn ko sọ fun aafin to fi lọọ pe awọn ọlọpaa.

Igbesẹ too gbe yii tabuku àpèrè Olubadan ati ilẹ Ibadan, igbimọ yii si ti paṣẹ pe ka fofin de ọ gẹgẹ bii Mọgaji Akinṣọla, ko o si tọrọ aforijin lọwọ awọn to o ṣẹ titi dasiko ta o fi yanju wahala to o da silẹ yii.”

 

Leave a Reply