Olubadan sọ baalẹ mẹrinlelọgbọn d’ọba alade n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun, ti fi awọn baalẹ mẹrinlelọgbọn (34) kaakiri ilẹ Ibadan jọba.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, layẹyẹ ọhun waye laafin Olubadan to wa l’Ọjaaba, nibi ti Ọba Balogun ti de awọn baalẹ ọhun lade, to si gbe ọpa aṣẹ le wọn lọwọ toun tilẹkẹ ọrun gẹgẹ bii iṣami ọba.

Awọn ọba ọhun lo yan kaakiri ijọba ibilẹ mẹfa niluu Ibadan.

Awọn ijọba ibilẹ ọhun ni Akinyẹle: Ido, Lagelu, Ẹgbẹda, ati Ọna-Ara; nibi ta a ti ri Ọba Lasisi Akano, to di Onijaye ti Ijaye; Ọba Ismaila Ọlasunkanmi Abioye Ọpẹọla (Oniroko tilu Iroko); Ọba Moses Ọlasunkanmi Akinyọsoye (Onikereku ti Ikereku); Ọba James Oluyẹmi Ọdẹniran (Alakinyẹle) ti Akinyẹle, ati Ọba Kareem Adigun to di Onimọniya ti Mọniya.

Awọn to di ọba nijọba ibilẹ Ọna Ara ni Ọba Adebọwale Kamorudeen Adeyẹmi, JP (Oniladuntan ti Laduntan) ati Ọba Mudasiru Musa (Alararọ ti Ararọ), Ọba Nureni Yusuf Adegbenro (Alajia ti Ajia Moja Opo), Ọba Muili Mosaderin (Ọlọlọṣunde ti Ọlọṣunde), Ọba Yẹkinni Obiṣẹsan (Alakanran ti Akanran), ati Ọba Richard Adeṣọkan Olunlọyọ (Ololunlọyọ ti Olunlọyọ) ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ṣaaju l’Olubadan, Ọba Lekan Balogun, ti kilọ fawọn ọba naa lati ma ṣe foju tẹnbẹlu awọn to ju wọn lọ ninu ilana eto oye jijẹ nilẹ Ibadan.

 

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “a mọ pe ọrọ awọn ilu kan ni awuyewuye ninu, sibẹsibẹ, a ṣeto agbega fun wọn nitori ta a ba kọ ta o ṣe e, awọn araalu ati idagbasoke awọn ilu wọnyi lo maa pa a lara. Gbogbo àyípadà tá a sì ṣe wọnyi, a ṣe e nitori ki itan le sọ rere nipa wa lọjọ iwaju ni”.

Leave a Reply