Oludije sipo gomina ẹgbẹ PDP, Jandor, ṣabẹwo s’obinrin tawọn tọọgi ṣe leṣe lọjọ idibo

Monisọla Saka

Oludije funpo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko, Abdulazeez Ọlajide Adediran, tawọn eeyan mọ si Jandor, ti ṣabẹwo sile Arabinrin Jennifer Efidi Seifegha, obinrin ti awọn janduku kọ lu lọjọ idibo aarẹ, ti wọn si ṣe leṣe yanna yanna.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii, llọ bẹ ẹ wo nitori ikọlu ti wọn ṣe si i lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu yii, lasiko ti eto idibo aarẹ n lọ lọwọ nibudo idibo wọn.

Jandor ṣalaye fawọn oniroyin nile obinrin naa to wa laduugbo Dipọ Olubi, Ikate, lagbegbe Surulere, nipinlẹ Eko, pe iwa akin tobinrin naa hu lati tun jade dibo lẹyin gbogbo ohun ti wọn e fun un jọ ohun loju pupọ, eyi lo si mu koun wa a wa.

O ni, “Mo wa lati waa yọju si obinrin to jẹwọ akọni ijọba awa-ara-wa, latari iwa akinkanju to hu, to jẹ ohun iwuri, to si yẹ keeyan fi ṣe awokọṣe. Fun eeyan to ṣeṣe to bẹẹ yẹn lati pada si ibudo idibo lati tẹka fun ẹni to wu u, iwa ki eeyan nifẹẹ orilẹ-ede ẹni lọkan ni, mo si mọ riri iwa to hu yii”.

Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ Ọgbẹni Christopher Seifegha, ti i ṣe ọkọ obinrin naa, fun bo ṣe gba iyawo ẹ laaye lati pada sibudo idibo, pẹlu gbogbo ọgbẹ to wa loju ẹ.

Ninu ọrọ to kọ sori ayelujara (Facebook)rẹ ni Jandor ti bu ẹnu atẹ lu iwa buruku tawọn eeyan ọhun hu, to si gboriyin fun obinrin naa pẹlu iwa akin to fi han, pẹlu bo ṣe pada lọọ tẹka lai wo ti nnkan toju ẹ ri ati ọgbẹ to gba nibi ikọlu ti wọn ṣe si i.

O ni, “Iṣẹlẹ ikọlu ta a ri kaakiri ipinlẹ Eko lọjọ Satide, jẹ ọkan lara awọn idi ta a fi gbe igbes, ta a si fi n ṣiṣẹ lati ri i daju pe a mi eemi alaafia simu nipinlẹ Eko, ati lati pe fun atunṣe ati ayipada ti yoo fopin si iwa awọn janduku ti wọn n lo awọn ọdọ wa gẹgẹ bii irinṣẹ buburu lati ja fun apo tiwọn.

Ko ti i ju bii oṣu meloo kan lọ bayii ta a kegbajare lori ọrọ iwa janduku ati ija lasiko ibo, tawọn ẹgbẹ oṣelu to wa nipo fi dena de Arabinrin Bina Jennifer Efidi, ti wọn si ṣe e leṣe pẹlu iwa ika wọn.

“Mo ṣabẹwo si i lonii lati gboṣuba nla fun un nitori iwa akinkanju ati ifayaran-iṣoro to fi han lati le ṣe ojuṣe rẹ gẹgẹ bii ọmọ Naijiria rere lojuna ati le ṣi awọn ika buburu, ti wọn n pe nijọba nidii kuro lori ipo’’.

Nigba to n ṣalaye bọrọ naa ṣe ṣẹlẹ, Arabinrin Jennifer Seifegha ni aago mẹsan-an aarọ loun de ibudo idibo oun to wa ni Wọọdu Nuru/Oniwo, ibudo idibo karundinlaaadọrin, lagbegbe Surulere, ipinlẹ Eko, lati ṣe ojuṣe oun.

O ni, “Lẹyin ti mo yẹ orukọ mi wo tan, mo to sori ila lati dibo. Nigba ti mo ri i pe awọn eeyan ko sun siwaju, oju kan naa ni gbogbo wa duro pa si, ni mo ba jokoo. Nibi ti mo jokoo si ni mo ti ri awọn ọkunrin kan ti wọn rọ de, o si jọ pe niṣe ni wọn waa yẹ ilẹ wo, nitori ko pẹ pupọ ti wọn tun fi kuro nibẹ.

Lẹyin bii wakati kan ni wọn tun pada de, bo ṣe di pe idarudapọ bẹ silẹ niyẹn, mo kan ri i pe nnkan kan ba mi loju lojiji ni”.

‘‘Mo ri i pe wọn fi nnkan gba mi loju, ẹjẹ si bẹrẹ si i da nibi ọgbẹ nla to da si mi loju naa. Obinrin kan ni Ọlọrun fi kẹ mi pẹlu bo ṣe fi aṣọ di mi loju lati da ẹjẹ to n da yaaya naa duro, lati ibẹ la ti lọ fara pamọ sibi kan nitori a ko mọ boya awọn janduku yẹn ṣi wa nitosi.

“Nigba ta a ri i pe gbogbo wahala yẹn ti rọlẹ, wọn mu mi lọ si ọdọ nọọsi alabẹrẹ kan nitosi ibẹ, nọọsi yẹn lo sare ba mi tọju oju ọgbẹ yẹn ti ẹjẹ fi duro. Lẹyin ẹ ni ọkọ mi gbe mi lọ si sibitu, nibi tawọn nọọsi ti ran oju ọgbẹ naa ni bii ọna marun-un “.

Obinrin yii ni oun ko mọ pe fidio oju oun yii ti rin jinna ni gbogbo igba naa. Arabinrin Jennifer waa dupẹ pupọ lọwọ Jandor fun abẹwo to ṣe si idile naa.

Leave a Reply