Olufọn: Ẹ ba wa sọ fun Oyetọla ko ma da wahala silẹ niluu wa o – Ile ọlọmọọba

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gbogbo awọn idile to n jọba niluu Ifọn-Orolu, nijọba ibilẹ Orolu, nipinlẹ Ọṣun, ti kilọ pe kijọba ma ṣe dawọ le ohunkohun to le da wahala silẹ niluu naa pẹlu ahesọ to n lọ kaakiri pe ijọba fẹẹ kede orukọ Olufọn ti Ifọn-Orolu.

Lasiko ifẹhonu han wọọrọwọ ti gbogbo aṣoju awọn idile maraarun ti wọn maa n jọba niluu naa; Ile Moronfolu, Olumoyero, Ọdunolu, Oriṣatoyinbo ati Oluyẹyin ṣe niwaju aafin Olufọn lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn ti sọ pe ko si afọbajẹ to fi orukọ ọmọ-oye kankan ranṣẹ sijọba, iyalẹnu lo si jẹ pe ijọba fẹẹ kede orukọ Olufọn tuntun.

Akọwe apapọ fun awọn ọlọmọọba naa, Ọmọọba Ọladepo Tunde Oyelade, ṣalaye pe bii igba tijọba mọ-ọn-mọ fẹẹ da omi alaafia ilu naa ru gẹgẹ bo ṣe n ṣẹlẹ lọwọlọwọ lawọn ilu kọọkan nipinlẹ Ọṣun ni igbesẹ ti wọn fẹẹ gbe.

Lati fi ọkan awọn araalu balẹ, ki wọn si ṣafọmọ ara wọn, Ọmọọba Ọladepo sọ pe ṣe ni kijọba kede fun gbogbo aye pe irọ to jinna soootọ ni ahesọ to n lọ kaakiri naa.

Idi eyi, gẹgẹ bo ṣe sọ, ni pe ẹjọ wa niwaju ile-ẹjọ giga ilu Oṣogbo lori ọrọ ipo Olufọn, koda, ọjọ kẹsan-an oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni ijokoo yoo waye laarin awọn agbẹjọro olujẹjọ ati olupẹjọ (Pre-Trial Conference) lori ẹ.

O ni ilu alaafia ni ilu Ifọn-Orolu, wọn si ni eto ti wọn fi maa n yan ọba wọn, yoo lewu funjọba lati ṣe ohunkohun to le da ogun tabi ọtẹ silẹ laarin ilu naa.

“A n fẹhonu han loni-in lati jẹ ki ijọba mọ pe a ko fara mọ fifi tipatipa yan Olufọn ti Ifọn Orolu fun wa. Lati le yanju gbogbo aawọ to wa nidii yiyan ọba tuntun la ṣe lọ si kootu, nitori naa, yoo ta ko ilana ofin tijọba ba gbe igbesẹ kankan lori ẹjọ to ti wa nile-ẹjọ.

“Nitori ahesọ ti a n gbọ yii la ṣe jade sita. A ko ni i faaye gba ẹnikẹni da wahala si wa lagbada. Ilu to wa leti aala ni Ifọn-Ọṣun to jẹ olu ilu ijọba ibilẹ wa, ti wahala kankan ba ṣẹlẹ, apa ijọba ko ni i ka a”.

Leave a Reply