Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Olujarẹ tilu Ijarẹ, Ọba Adebamigbe Oluwagbemigun, Kokotiri keji la gbọ pe o ti waja lẹni ọdun mẹtalelọgọrin.
Ṣapetu ilu Ijarẹ, Oloye Wẹmimọ Ọlaniran, lo fidi Ipapoda ọba alaye ọhun mulẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ lati ẹnu araalu kan to ni ka forukọ bo oun lasiiri, o ni alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, lokiki kọkọ kan jake-jado ilu pe Ọba Adegbemigun ti waja, ṣugbọn tawọn Oloye kan sare jade lati ta ko ọrọ naa, ti wọn si juwe iroyin ọhun bii ahesọ lasan.
Ọrọ yii lo ni ko ṣee fọwọ bo mọ laaarọ ọjọ keji tii ṣe ọjọ Ẹti, Furaidee, latari bi iroyin naa ti ṣe tan kalẹ kọja bo ṣe yẹ.
Ọba Adegbemigun gori itẹ awọn baba nla rẹ lọdun 1996 gẹgẹ bii Olujarẹ ti Ijarẹ, nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ.
Ọdun to kọja ni aara san pa awọn maaluu bii ogoji niluu ọhun lẹyin tawọn Fulani to n da wọn ko wọn lọọ jẹ lagbegbe Oke-Ọwa, niluu Ijarẹ, oṣu diẹ lẹyin eyi ni kabiyesi ọhun tun gbẹsẹ le awọn maaluu bii aadọrin lẹyin ti wọn lọọ jẹ oko oloko.
Awọn iṣẹlẹ wọnyi wa lara ohun to sọ ọba naa di olokiki jake-jado orilẹ-ede yii, tọpọ eeyan si n wo o bii akikanju ati alagbara.
Ni ibamu pẹlu aṣa ati iṣẹdalẹ ilu ọhun, Oloye Salọtun ni yoo maa tukọ ilu gẹgẹ bii adele titi digba ti wọn yoo fi yan ọba mi-in.