Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni olukọ Fasiti ipinlẹ Kwara (KWASU), kan, Ọgbẹni Idris Ọladimeji Yahaya, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, pade iku ojiji l’Opopona Malete si ilu Ilọrin, nipinlẹ naa.
ALAROYE gbọ pe Yahaya jẹ olukọ lẹka imọ ẹkọ nipa oṣelu (Political Science), ni ileewe ọhun, to si padanu ẹmi rẹ lasiko to kuro nileewe to n pada si Ilọrin.
Giiwa agba fasiti ọhun, Ọjọgbọn Muhammed Mustapha Akanbi SAN, kẹdun pẹlu mọlẹbi oloogbe, o ni pẹlu ibanujẹ ati ẹdun ọkan ni ohun fi kede iku Yahaya. O gbadura pe ki Ọlọrun rọ awọn mọlẹbi rẹ loju, ko si tẹ oloogbe si afẹfẹ rere. O waa rọ gbogbo awọn oṣiṣẹ fasiti naa lati gbadura fun mọlẹbi ẹni ire to lọ.