Faith Adebola
Lasiko ibẹrẹ iṣẹ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, ẹlẹẹkẹwa iru rẹ, awọn aṣofin naa ti yan awọn ijoye ile ti yoo maa tukọ wọn niṣo. Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ, to n ṣoju awọn eeyan agbegbe Ifọ, to ti wa nipo olori wọn tẹlẹ naa ni wọn tun fibo gbe wọle sipo ọhun bayii.
Inu gbọngan apero awọn aṣofin naa, eyi to wa nile ijọba, l’Oke-Mọsan, l’Abẹokuta, ni eto naa ti waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni eto naa ti kọkọ fẹẹ waye, ṣugbọn latari bi ẹkọ ko ṣe ṣoju mimu lọjọ naa fun Ọnarebu Oluọmọ to n dije lati pada sipo olori ile, tawọn aṣofin kan ti wọn ko nifẹẹ si ipada-sipo rẹ si ti mura lati gbegi dina fun un, ati eto aabo ti ko da ni loju lọjọ naa, lo mu ki wọn so iyansipo ọhun rọ, ti wọn sun un siwaju di ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ ogunjọ, oṣu Kẹfa yii.
O jọ pe inu ibẹru pe awọn kan le fẹẹ dana ijangbọn silẹ lo mu ki wọn ro eto aabo ọjọ naa le dan-in, bo tilẹ jẹ pe Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ko yọju sibi iyansipo ọhun.
Ki wọn too bẹrẹ eto naa ni nnkan bii aago meji ọsan ku iṣẹju mẹwaa, awọn aṣofin ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni wọn kọkọ n ṣe oniruuru ipade idankọkọ laarin ara wọn, bi wọn ṣe n lọ ni wọn n bọ, ti wọn si n pe biri-koto ba ara wọn sọrọ.
Lopin ohun gbogbo, ko sẹni to dije fun ipo olori ile naa pẹlu Ọlakunle Oluọmọ, ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, niṣe ni gbogbo wọn panu-pọ yan an sipo, to si di olori wọn.
Lẹyin eyi lawọn aṣofin naa lọọ ba Gomina Abiọdun lalejo lọfiisi rẹ ti ko fi bẹẹ jinna sileegbimọ awọn aṣofin naa, gomina si ba wọn sọrọ tutu, o loun ko ni i fi ti ẹgbẹ oṣelu ṣe ninu ajọṣe oun pẹlu awọn aṣofin ọhun, o ni gomina fun gbogbo eeyan loun maa jẹ.
Ẹ oo ranti pe mẹtadinlogun lara awọn aṣofin ipinlẹ Ogun lo jẹ ọmọ ẹgbẹ APC, nigba tawọn mẹsan-an wa latinu ẹgbẹ oṣelu PDP.