Stephen Ajagbe, Ilorin
Nitori iwa ijọra ẹni loju, jagidijagan ati dida ilu ru, Olusin tilu Isanlu-Isin, nipinlẹ Kwara, Ọba Solomon Olugbenga Oloyede, ti fontẹ lu rirọ Oloye giga, Ọlọgba ti Isanlu-Isin, Ọlaniyi Alade loye.
Alade jẹ oloye to wa nipo kẹta si ọba ilu naa. Ọpọlọpọ araalu, paapaa awọn ọdọ, ni wọn fẹhonu han ta ko iwa ti ọkunrin naa n hu laarin ilu.
Ki kabiyesi atawọn oloye ilu too fontẹ lu irọloye rẹ, awọn ibatan rẹ nile Ọlọgba to ti wa ti fi ẹjọ rẹ sun ilu, ti wọn si ni gbogbo igbesẹ to n gbe ko dun mọ awọn ninu.
Ọba Oloyede ti waa ṣekilọ fun Alade lati yee pe ara rẹ ni oloye ilu, bi bẹẹ kọ, wọn yoo fi pampẹ ofin gbe e.
“Ọpọlọpọ awọn ara Ile Ologba ni wọn ti gbe ọrọ rẹ wa si aafin. Wọn ni gbogbo ọna lo fi n ta ko idagbasoke ati ilọsiwaju ilu. Wọn tun fẹsun kan an pe lati bii ogun ọdun to ti wa nipo, ko fa eeyan kankan kalẹ ri lati jẹ oye niluu. Dipo bẹẹ, wọn lo maa n lo ipo rẹ gẹgẹ bii oloye giga lati maa fi halẹ mọ awọn eeyan, tẹ wọn loju mọlẹ, o si tun n fi ipo rẹ gba ilẹ lọwọ wọn.
Ṣugbọn, Oloye Alade ni awada lasan ni wọn n ṣe. O ni oun ṣi ni Ọlọgba tilu Isanlu-Isin.