Oluwoo pe awọn onimọ nipa ede Yoruba nija

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, ti kegbajare pe ede Yoruba ti n rokun igbagbe diẹdiẹ nipasẹ rirọgbọku le ede Oyinbo, o si ke si awọn onimọ ijinlẹ lati tete wa nnkan ṣe si eleyii.

Ọba Akanbi sọrọ yii laafin rẹ lasiko to n gbalejo awọn mọlẹbi akọtan-an nni, Oloogbe Daniel Fagunwa, lori ara ayẹyẹ lati ṣeranti ọgọta ọdun ti baba naa jade laye.

Gẹgẹ bi Oluwoo ṣe wi, awọn onimọ ninu ede Yoruba ko ṣafikun ede naa, bi awọn baba nla wa ṣe fi silẹ naa lo wa titi di asiko yii.

O ni, “A ko mu igbelarugẹ ba ede Yoruba. Ko si afikun rara si eyi ti awọn baba nla wa ti fi silẹ, a si ti n pariwo fun awọn onimọ ninu ede Yoruba lati ji giri.

“O yẹ ki awa naa ti maa lo ede Yoruba lati yanju ohun to ba diju ninu ẹkọ Chemistry ati Physics. Awọn orileede nla bii Faranse ati Ṣaina ko nilo ede oyinbo lati yanju iṣoro imọ sayẹnsi wọn. Nigba wo lawa naa fẹẹ lo ede wa lọba ti yoo nitumọ?

“Ede Yoruba ti gbara le ede Oyinbo ju. Awọn obi ko le fi Yoruba geere ba awọn ọmọ wọn sọrọ mọ lai ṣe amulumọla ede Oyinbo nibẹ, iṣoro nla ni eleyii jẹ fun wa”.

Nigba ti Ọba Akanbi n sọrọ nipa Oloogbe Fagunwa, o ni iṣẹ baba naa n sọrọ lẹyin rẹ bo tilẹ ti ku, o si ke si awọn eeyan lati ṣawọkoṣe rẹ.

O ni, “Baba Fagunwa jẹ ẹni takuntakun ti a ba n sọrọ nipa iwe kikọ. Iwe rẹ kọ wa ni oniruuru ẹkọ. O ti kọ itan tirẹ, awa lo ku lati kọ itan ti ara wa.”

Ninu ọrọ rẹ, ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe Fagunwa, Ọladipọ Fagunwa ṣapejuwe baba rẹ bii ẹni ti ko wa ile aye mọya rara, to si nifẹẹ pupọ si aṣa ati iṣe Yoruba.

Ọladipọ sọ siwaju pe, ‘Baba jẹ ọlọyaya to ko gbogbo awa ọmọ rẹ mọra. Awada wọn pọ. Wọn ti figba kan gbagbe mọto wọn sibi ti wọn ti lọọ ra agbado, wọn si fi ẹsẹ rin wale, bi wọn ṣe ri niyẹn.’

Nibi eto naa ni awọn ẹgbẹ oṣere Imọdoye ti ṣafihan ọkan lara awọn iṣẹ Baba Fagunwa, iyẹn Aditu Olodumare.

Leave a Reply