Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye, Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, ti kede pe ọjọ kọkandinlogun, oṣu ti a wa yii ni ayẹyẹ igbeyawo alarinrin yoo waye laarin rẹ ati ọmọọbabinrin ilu Kano kan, Fardauz.
Ninu ọrọ ti Ọba Adewale fi sita, o ni iyawo gidi, aya rere lọọdẹ ọkọ ati oniwarere, ti wọn bi lati ile rere ni olori tuntun naa.
O ni ninu ile Mardakin Kano, lagbegbe Yola Quarters, niluu Kano, ni ayẹyẹ naa yoo ti waye laago mọkanla aarọ.
Lẹyin eyi ni apejẹ yoo waye laafin Emir Kano, HRH Alhaji Aminu Ado Bayero, fun awọn eeyan perete ni aago mẹrin irọlẹ ọjọ naa.
A gbọ pe nigba ti wọn ba gbe iyawo de ipinlẹ Ọṣun ni ayẹyẹ nla yoo waye fun gbogbo awọn ololufẹ Ọba Akanbi lati ki iyawo ọṣingin naa kaabọ.