Faith Adebọla, Eko
Ọmọọdun mejidinlogun (18) pere ni Samuel Adetomi tọwọ awọn ọlọpaa ikọ ayara-bii-aṣa RRS (Rapid Response Squard) ba lọsẹ to kọja yii nibi to ti n ja awọn onimọto lole lalẹ, ọkunrin naa sọ pe ole toun ki i ṣe akọsẹba tabi eeṣi lasan, dadi oun dira foun pẹlu oogun abẹnugọngọ koun too wa s’Ekoo ni, bọtu wọta (bottle water) loun maa n ta lọsan-an, idigunjale loun n f’alẹ ati oru ṣe.
Alaye ti CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi to jẹ ọga agba ikọ RRS ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lori iṣẹlẹ ọhun ni pe ori biriiji Ọtẹdọla, lọna marosẹ Ojodu si Berger, nipinlẹ Eko, lawọn ti mu afurasi ọdaran naa lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun yii.
O ni mẹrin lawọn ọmọ ole tawọn ọlọpaa ri nibi ti wọn ti n fipa gba owo ati foonu lọwọ awọn onimọto ninu sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ ọkọ to ṣẹlẹ lalẹ ọjọ naa, ṣugbọn bawọn ọlọpaa ṣe bẹ bọọlẹ ninu ọkọ wọn lati mu awọn afurasi ọdaran yii, niṣe lawọn naa bẹ danu bi wọn ṣe ri wọn, mẹta ninu wọn si sa lọ. Wọn ọkan tiẹ bẹ latori biriiji ọhun sinu ira nisalẹ.
Ṣugbọn orukọ ko ro Samuel ni tiẹ, Samuel o ribi sa, wọn mu un, wọn si fi pampẹ ofin gbe e. Ki wọn too mu oun naa, iṣẹ aṣelaagun ni wọn lawọn ọlọpaa ṣe, tori ọlọpaa bii mẹfa lo rẹn ọkunrin naa mọlẹ ki wọn too le fi ankọọfu si i lọwọ, lẹsẹ. Ọpọlọpọ igbo ati amuku igbo ni wọn ba lapo ẹ, pẹlu awọn oogun abẹnugọngọ oriṣiiriṣii.
Teṣan ọlọpaa ti wọn wọ ọ lọ lo ti jẹwọ pe oriṣiiriṣii gbẹrẹ ni baba oun ti sin sara oun, titi kan oruka toun wọ si atampako ẹsẹ osi oun.
O lọmọ bibi ilu Abeokuta loun, baba oun si ti se oun jinna koun too wa s’Ekoo lọdun to kọja. O lawọn oogun abẹnugọngọ naa lo maa n fun oun lagbara, toun fi le ṣe bii ọkunrin loju ija.
O loun o nile pato toun n gbe, ori biriiji ẹlẹsẹ loun maa n sun, adagun omi to wa labẹ biriiji naa loun si ti n wẹ. Iwọnba aṣọ polo meji toun ni loun fi n paarọ ara wọn, niṣe loun n fi owo toun ba ri nidii iṣẹ ole, jẹun.
Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ti ni kawọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti tubọ ṣiṣẹ iwadii, ki wọn si mu awọn yooku to sa lọ. O lawọn maa foju wọn bale-ẹjọ laipẹ.