Ọmọ Boko Haram yii sa lọ sọdọ awọn ṣọja: Ẹ ṣaanu mi, mi o fẹẹ fẹmi alaiṣẹ ṣofo mọ

Adewale Adeoye

Lara pe akitiyan awọn ṣọja orileede Naijiria ti n sọ eeso rere lo mu ki ogbologboo ọmọ ẹgbẹ afẹmiṣofo kan ti wọn n pe ni Boko Haram, nipinlẹ Borno, Alhaji Wosai, ṣe lọọ juwọ silẹ fawọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede yii lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun yii, to si loun ko ṣẹgbẹ buruku ọhun mọ rara.

Ikọ ọmọ ogun orileede yii kan ti wọn n pe ni ‘Operation Hadin Kai’ ti ‘21 Armored Brigade’, to n daabo bo awọn ara agbegbe Borno, ni Wosai lọọ juwọ ara rẹ silẹ fun, to si ṣeleri pe lae, oun ko tun ni i ba wọn fẹmi awọn alaiṣẹ ṣofo mọ.

ALAROYE gbọ pe gbara ti afurasi ọdaran ọhun ti sa kuro ninu ikọ rẹ to wa lagbegbe Garno, nipinlẹ Borno, nibi tawọn yooku rẹ tẹdo si lo ti mori le ọna ọdọ awọn ọmọ ogun orileede wa, to si ṣalaye lẹkunrẹrẹ fun wọn idi to ṣe kuro ninu ẹgbẹ rẹ.

Lara awọn ohun ija oloro ti afurasi ọdaran ọhun ko fawọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede yii ni ibọn AK 47 mẹta, ọpọlọpọ ọta ibọn atawọn ohun ija oloro mi-in.

Ṣa o, ọdọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun kan to n ṣewadii awọn afurasi ọdaran ni Wosai wa bayii, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo daadaa lati mọ boya loootọ lo tinu rẹ wa lati waa juwọ ara rẹ silẹ fawọn ṣọja

Eyi ki i ṣe igba akọkọ tawọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ma waa juwọ ara wọn silẹ fawọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede yii, awọn kan naa waa juwọ ara wọn silẹ loṣu Kẹrin, ọdun yii, nigba ti nnkan ko fara rọ mọ fun wọn ninu aginju ti wọn wa.

Leave a Reply