Ọmọ ẹgbẹ Labour balẹ sọsibitu, awọn tọọgi lo lu u lalubami l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour Party nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ileṣa, ti ke si Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Sunday Falẹyẹ, lati gba wọn lọwọ awọn tọọgi oloṣelu ti wọn n fojoojumọ jẹ wọn niya lagbegbe naa.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn ti awọn tọọgi naa ṣe leṣe laipẹ yii, Rabiu Ismaila, ṣe ṣalaye, o ni posita oludije ẹgbẹ Labour Party fun ipo ileegbimọ aṣoju-ṣofin lagbegbe naa loun fẹẹ lẹ ti awọn tọọgi naa fi ya bo oun.

O ni gbogbo igba ni wọn maa n kọ lu awọn ọmọ ẹgbẹ awọn ni adugbo Owode, Igangan ati Ọlọpọn, nilẹ Ijeṣa, ẹẹmẹta ni wọn si ti ba wọn fa wahala laarin ọsẹ kan pere.

Ismaila fi kun ọrọ rẹ pe oun ṣi n gba itọju lọwọ ni Wesley Guild Hospital, niluu Ileṣa, latari nina ti awọn tọọgi naa lu oun. O ni lati ilu Iwara lni wọn ti wa.

O ni “Ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni wọn ṣe mi leṣe nitori pe mo n lẹ posita ipolongo ibo oludije sipo ileegbimọ aṣoju-ṣofin lati agbegbe wa, Kunle Gideon, ti gbogbo eeyan mọ si Alọba. Ẹṣẹ kan ṣoṣo ti mo ṣẹ wọn niyẹn. Inu ibẹrubojo la n gbe bayii.

Ẹlomiran ti wọn tun fọwọ ba, ṣugbọn ti ko fẹẹ darukọ ara rẹ ṣalaye pe aago mọkanla alẹ ni wọn wa sile oun ni Ọlọpọn Ajegunlẹ, lọjọ ti wọn wa, bi wọn si ṣe ja ilẹkun wọle ni wọn bẹrẹ si i ba gbogbo dukia oun jẹ, ori lo si ko oun atawọn mọlẹbi oun yọ lọjọ naa.

O waa parọwa si ileeṣẹ ọlọpaa lati tete wa nnkan ṣe lori iṣẹlẹ naa nitori agbara awọn ọlọpaa ti wọn wa lagbegbe ọhun ko ka a mọ.

Alaga ẹgbẹ oṣelu Labour Party nipinlẹ Ọṣun, Comreedi Bello Adebayọ, waa ke si Kọmiṣanna Sunday Falẹyẹ lati fi panpẹ ofin gbe awọn tọọgi naa, ki wọn si fimu kata ofin.

Leave a Reply